Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Dáníẹ́lì 5:19-31 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

19. Nítorí ipò ńlá tí a fi fún un, gbogbo ènìyàn orílẹ̀ èdè àti èdè gbogbo fi ń páyà tí wọ́n sì ń bẹ̀rù rẹ̀. Ó ń pa àwọn tí ó bá wù ú, ó sì ń dá àwọn tí ó bá wù ú sí, ó ń gbé àwọn tí ó bá wù ú ga, ó sì ń rẹ àwọn tí ó bá wù ú sílẹ̀.

20. Ṣùgbọ́n nígbà tí ọkàn rẹ̀ ga, tí ó sì le koko. Ó bẹ̀rẹ̀ sí i hùwà ìgbéraga, a mú u kúrò lórí ìtẹ́ ọba rẹ̀, a sì gba ògo rẹ̀ kúrò.

21. A lé e kúrò láàrin ènìyàn, a sì fún un ní ọkàn ẹranko; ó sì ń gbé pẹ̀lú àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, ó sì ń jẹ koríko bí i ti màlúù; ìrì ọ̀run sì ṣẹ̀ sí ara rẹ̀, títí tó fi mọ̀ pé, Ọlọ́run Ọ̀gá Ògo ń jọba lórí ìjọba ọmọ ènìyàn, òun sì ń fi fún ẹni tí ó bá wù ú.

22. “Ṣùgbọ́n ìwọ ọmọ rẹ̀, Beliṣáṣárì, ìwọ kò rẹ ara à rẹ sílẹ̀, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìwọ mọ nǹkan wọ̀nyí.

23. Dípò èyí, ìwọ gbé ara à rẹ ga sí Olúwa ọ̀run, a mú kọ́ọ̀bù inú tẹ́ḿpìlì rẹ̀ wá sí iwájú ù rẹ, ìwọ àti àwọn ìjòyè rẹ, àwọn ìyàwó ò rẹ àti àwọn àlè rẹ fi ń mu wáìnì. Ìwọ ń yin àwọn òrìṣà fàdákà àti wúrà, idẹ, irin, igi àti ti òkúta, èyí tí kò lè ríran, tí kò le è gbọ́ran tàbí ní òye nǹkan kan. Ṣùgbọ́n ìwọ kò bu ọlá fún Ọlọ́run ẹni tó ni ẹ̀mí ì rẹ lọ́wọ́, tí ó sì mọ gbogbo ọ̀nà rẹ.

24. Nítorí náà, ó rán ọwọ́ tí ó kọ àkọlé yìí.

25. “Èyí ni àkọlé náà tí a kọ:MENE, MENE, TÉKÉLÌ, PÉRÉSÍNÌ

26. “Èyí ni nǹkan tí ọ̀rọ̀ náà túmọ̀ sí: Mene: Ọlọ́run ti sírò ọjọ́ ìjọba rẹ. Ó sì ti mú u wá sí òpin.

27. Tékélì: A ti gbé ọ lórí òṣùwọ̀n, ìwọ kò sì tó ìwọ̀n.

28. Pérésínì: A ti pín ìjọba rẹ a sì ti fi fún àwọn Médíà àti àwọn Páṣíà.”

29. Nígbà náà ni Beliṣáṣárì pàṣẹ pé kí a wọ Dáníẹ́lì ní aṣọ eléṣèé àlùkò, kí a sì fi ẹ̀gbà wúrà sí i lọ́rùn, a sì kéde rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí olórí kẹta ní ìjọba rẹ̀.

30. Ní alẹ́ ọjọ́ náà ni a pa Beliṣáṣárì, ọba Bábílónì.

31. Dáríúsì ará Médíánì sì gba ìjọba nígbà tí ó di ọmọ ọdún méjìlélọ́gọ́ta (62).

Ka pipe ipin Dáníẹ́lì 5