Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Dáníẹ́lì 5:1-5 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Beliṣáṣárì, ọba ṣe àsè ńlá fún ẹgbẹ̀rún (1,000) kan nínú àwọn ọlọ́lá a rẹ̀, ó sì mu wáìnì pẹ̀lú u wọn.

2. Bí Beliṣáṣárì ṣe ń mu wáìnì, ó pàṣẹ pé kí wọn kó kọ́ọ̀bù wúrà àti ti fàdákà wá, èyí tí Nebukadinéṣárì bàbá rẹ̀ kó wá láti inú tẹ́ḿpìlì ní Jérúsálẹ́mù, kí ọba àti àwọn ọlọ́lá a rẹ̀, àwọn ìyàwó àti àwọn àlè rẹ̀ kí ó ba à le fi mu wáìnì.

3. Wọ́n sì kó kọ́ọ̀bù wúrà àti fàdákà àti fàdákà èyí tí wọ́n kó jáde láti inú tẹ́ḿpìlì, ilé Ọlọ́run ní Jérúsálẹ́mù, ọba àti àwọn ìjòyè rẹ̀, àwọn ìyàwó àti àwọn àlè rẹ̀, sì fi mu wáìnì.

4. Bí wọ́n ṣe ń mu wáìnì bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ń yin òrìṣà wúrà àti fàdákà, ti idẹ, irin, igi àti òkúta.

5. Lójijì, ìka ọwọ́ ènìyàn jáde wá, ó sì ń kọ̀wé sára ẹfun ògiri ní ẹ̀gbẹ́ ibi tí àtùpà ń dúró ní ààfin ọba. Ọba ń wo ọwọ́ náà bí ó ṣe ń kọ ọ́.

Ka pipe ipin Dáníẹ́lì 5