Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Dáníẹ́lì 12:7-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

7. Ọkùnrin tí ó wọ aṣọ àlà, ẹni tí ó wà lórí omi odò, gbé ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ àti ọwọ́ òsì rẹ̀, mo gbọ́ tí ó fi ẹni tí ó wà títí láé búra, ó sọ wí pé, “Yóò ṣe ní àkókò kan, àkókò méjì àti ààbọ̀. Nígbà tí agbára àwọn ẹni mímọ́ yóò ti fọ́ tán pátapáta, gbogbo nǹkan wọ̀nyí yóò sì parí.”

8. Èmi gbọ́, ṣùgbọ́n kò yé mi. Nígbà náà ni mo bèèrè pé, “Olúwa mi, kí ni yóò jẹ́ àbábọ̀ àwọn nǹkan wọ̀nyí?”

9. Ó sì dáhùn pé, “Má a lọ ní ọ̀nà rẹ, Dáníẹ́lì nítorí tí a ti pa ọ̀rọ̀ náà dé, a sì ti fi èdìdì dìí di ìgbà ìkẹyìn.

10. Ọ̀pọ́lọpọ̀ ni a ó fọ̀ mọ́, wọn yóò wà láì lábàwọ́n, a ó sì tún wọn ṣe, ṣùgbọ́n àwọn ẹni búburú yóò máa ṣe búburú lọ, kò sí ẹni búrurú tí òye yóò yé ṣùgbọ́n òye yóò yé àwọn ọlọ́gbọ́n.

11. “Láti àkókò tí a ó mú ẹbọ ojoojúmọ́ kúrò, tí a ó sì gbé ìríra tí ó ń fa ìsọdahoro kalẹ̀ yóò sì jẹ́ ẹgbẹ̀rún àti igba lé àádọ́rùn-ún ọjọ́ (1,290).

12. Ìbùkún ni fún ẹni tí ó dúró tì ọ́ àti tí ó sì di òpin ẹgbẹ̀rún àti ọ̀ọ́dúnrún lé àrùndínlógójì ọjọ́. (1,335)

13. “Ṣùgbọ́n ìwọ, máa lọ ní ọ̀nà rẹ, títí di òpin. Ìwọ yóò sinmi, àti ní òpin ọjọ́ ìwọ yóò dìde láti gba èrè rẹ.”

Ka pipe ipin Dáníẹ́lì 12