Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Dáníẹ́lì 12:1-6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. “Ní àkókò náà, ni Máíkẹ́lì, ọmọ aládé ńlá, ẹni tí o n dáàbò bo àwọn ènìyàn an rẹ̀, yóò dìde. Àkókò ìpọ́njú yóò wà, irú èyí tí kò tíì ṣẹlẹ̀ rí láti ìbẹ̀rẹ̀ àwọn orílẹ̀ èdè títí di àkókò náà. Ṣùgbọ́n ní àkókò náà àwọn ènìyàn rẹ̀, gbogbo àwọn tí a bá ti rí orúkọ wọn nínú ìwé ni a ó gbàlà.

2. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn tí ó sùn nínú erùpẹ̀ ilẹ̀ ni yóò jí: àwọn mìíràn sí ìyè àìnípẹ̀kun, àwọn tókù sí ìtìjú àti sí ẹ̀gàn àìnípẹ̀kun.

3. Àwọn tí ó jẹ́ ọlọgbọ́n yóò máa tàn bí ìmọ́lẹ̀ ọ̀run, àti àwọn tí ó ń tọ́nisọ́nà sí òdodo, yóò máa tàn bí ìràwọ̀ láé àti láéláé.

4. Ṣùgbọ́n ìwọ Dáníẹ́lì, pa ìwé náà dé kí o sì pa ọ̀rọ̀ ọ rẹ̀ mọ́ títí àkókò ìgbẹ̀yìn. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ yóò máa lọ sí ìhín sí ọ̀hún láti jẹ́ kí ìmọ̀ wọn di púpọ̀.”

5. Nígbà náà, ni èmi Dáníẹ́lì, wò, ní iwájú mi àwọn méjì mìíràn dúró, ọ̀kan dúró sí apá ìhín ní etí bèbè odò ẹnìkan náà ní apá ọ̀hún etí i bèbè.

6. Ọ̀kan lára wọn sọ fún ọkùnrin tí ó wọ aṣọ àlà, ẹni tí ó wà lórí omi odò pé, “Báwo ni yóò ṣe pẹ́ tó kí àwọn nǹkan ìyanu wọ̀nyí tó wá sí ìmúṣẹ?”

Ka pipe ipin Dáníẹ́lì 12