Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Dáníẹ́lì 10:1-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ní ọdún kẹta Sárúsì ọba Páṣíà, a fi ìran kan hàn Dáníẹ́lì (ẹni tí à ń pè ní Bélítésásárì). Òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ ìran náà, ó sì ní í ṣe pẹ̀lú àsìkò ìpọ́njú ńlá, òye ọ̀rọ̀ náà wá bá a nínú ìran.

2. Ní àsìkò náà, èmi Dáníẹ́lì ṣọ̀fọ̀ fún ọ̀sẹ̀ mẹ́ta.

3. Èmi kì í jẹ oúnjẹ tí ó dára, èmi kò fi ẹran tàbí wáìnì kan ẹnu mi, bẹ́ẹ̀ ni èmi kò fi òróró para títí ọ̀sẹ̀ mẹ́ta fi kọjá.

4. Ní ọjọ́ kẹrìnlélógún oṣù àkọ́kọ́, bí mo ti dúró sí etí i bèbè odò ńlá Tígírísì,

5. Mo wo òkè, mo rí ọkùnrin kan tí ó wọ aṣọ àlà funfun, pẹ̀lú àmùrè wúrà dáradára ni ó fi di ẹ̀gbẹ́.

6. Ara rẹ̀ dàbí báálì, ojú u rẹ̀ dàbí mọ̀nàmọ́ná, ẹyin ojú u rẹ̀ dàbí iná àtẹ̀tàn, apá àti ẹṣẹ̀ rẹ̀ dàbí ìtànná ìmọ́lẹ̀ tí o kún fún idẹ, àti ohùn rẹ̀ dàbí i ti ìjọ ènìyàn púpọ̀.

7. Èmi Dáníẹ́lì, ni ẹnìkan tí ó rí ìran náà, àwọn ọkùnrin tí ó wà pẹ̀lú u mi, wọn kò rí i, ṣùgbọ́n ìpayà ńlá dà bò wọ́n, wọ́n sálọ wọ́n sì fi ara pamọ́.

8. Ó sì ku èmi nìkan, tí mo rí ìran ńlá yìí, kò sì ku ohun kankan fún mi, ojú u mi sì rẹ̀wẹ̀sì gidigidi, n kò sì ní agbára mọ́.

9. Nígbà náà, ni mo gbọ́ tí ó ń sọ̀rọ̀, bí mo ṣe tẹ́tí sílẹ̀ síi, mo ṣùn lọ fọnfọn, ní ìdojúbolẹ̀.

Ka pipe ipin Dáníẹ́lì 10