Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àìsáyà 9:1-8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ṣíbẹ̀ṣíbẹ̀, kò ní sí ìpòrúurù kan kan mọ́ fún àwọn tí ó wà nínú ìbànújẹ́. Nígbà kan rí ó rẹ ilẹ̀ Sẹbúlúnì sílẹ̀ àti ilẹ̀ Nápítalì pẹ̀lú, ṣùgbọ́n ní ọjọ́ iwájú, yóò bu ọ̀wọ̀ fún Gálílì ti àwọn aláìkọlà, ní ọ̀nà òkun, ní ẹ̀gbẹ̀ẹ̀gbẹ́ Jọ́dánì.

2. Àwọn ènìyàn tí ń rìn nínú òkùnkùnti rí ìmọ́lẹ̀ ńlá;Lórí àwọn tí ń gbé ní ilẹ̀ òjìji ikú niìmọ́lẹ̀ ti ràn.

3. Ìwọ ti sọ orílẹ̀-èdè di ńlá;wọ́n sì yọ̀ níwájúu rẹgẹ́gẹ́ bí àwọn ènìyàn ti í yọ ayọ̀ ìkóórè,gẹ́gẹ́ bí ènìyàn ti í yọ̀nígbà tí à ń pín ìkógun.

4. Nítorí gẹ́gẹ́ bí ọjọ́ tí a ṣẹ́gun Mídíánì,ìwọ ti fọ́ ọ túútúúúàjàgà ti ń pa wọ́n lẹ́rù,ọ̀pá tí ó dábùú èjìká wọn,ọ̀gọ aninilára wọn.

5. Gbogbo bàtà jagunjagun tí a ti lò lójú ogunàti gbogbo ẹ̀wù tí a yí nínú ẹ̀jẹ̀,ni yóò wà fún ìjóná,àti ohun èlò iná dídá.

6. Nítorí a bí ọmọ kan fún wa,a fi ọmọkùnrin kan fún wa,ìjọba yóò sì wà ní èjìkáa rẹ̀.A ó sì má a pè é ní: ÌyanuOlùdámọ̀ràn, Ọlọ́run AlágbáraBaba ayérayé, Ọmọ ọba aládé Àlàáfíà.

7. Ní ti ìgbòòrò Ìjọba rẹ̀ àti àlàáfíà rẹ̀ ni kì yóò ní ìpẹ̀kun.Yóò jọba lórí ìtẹ́ Dáfídìàti lórí ẹ̀kún un rẹ̀ gbogbo,nípa ìfìdímúlẹ̀ àti ìgbéró rẹ̀,pẹ̀lú òtítọ́ àti òdodoláti ìgbà náà lọ àti títí láéláé.Ìtara Olúwa àwọn ọmọ-ogunni yóò mú èyi ṣẹ.

8. Olúwa ti dojú iṣẹ́ kan kọ Jákọ́bù;Yóò sì wá sórí Ísírẹ́lì.

Ka pipe ipin Àìsáyà 9