Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àìsáyà 9:1-6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ṣíbẹ̀ṣíbẹ̀, kò ní sí ìpòrúurù kan kan mọ́ fún àwọn tí ó wà nínú ìbànújẹ́. Nígbà kan rí ó rẹ ilẹ̀ Sẹbúlúnì sílẹ̀ àti ilẹ̀ Nápítalì pẹ̀lú, ṣùgbọ́n ní ọjọ́ iwájú, yóò bu ọ̀wọ̀ fún Gálílì ti àwọn aláìkọlà, ní ọ̀nà òkun, ní ẹ̀gbẹ̀ẹ̀gbẹ́ Jọ́dánì.

2. Àwọn ènìyàn tí ń rìn nínú òkùnkùnti rí ìmọ́lẹ̀ ńlá;Lórí àwọn tí ń gbé ní ilẹ̀ òjìji ikú niìmọ́lẹ̀ ti ràn.

3. Ìwọ ti sọ orílẹ̀-èdè di ńlá;wọ́n sì yọ̀ níwájúu rẹgẹ́gẹ́ bí àwọn ènìyàn ti í yọ ayọ̀ ìkóórè,gẹ́gẹ́ bí ènìyàn ti í yọ̀nígbà tí à ń pín ìkógun.

4. Nítorí gẹ́gẹ́ bí ọjọ́ tí a ṣẹ́gun Mídíánì,ìwọ ti fọ́ ọ túútúúúàjàgà ti ń pa wọ́n lẹ́rù,ọ̀pá tí ó dábùú èjìká wọn,ọ̀gọ aninilára wọn.

5. Gbogbo bàtà jagunjagun tí a ti lò lójú ogunàti gbogbo ẹ̀wù tí a yí nínú ẹ̀jẹ̀,ni yóò wà fún ìjóná,àti ohun èlò iná dídá.

6. Nítorí a bí ọmọ kan fún wa,a fi ọmọkùnrin kan fún wa,ìjọba yóò sì wà ní èjìkáa rẹ̀.A ó sì má a pè é ní: ÌyanuOlùdámọ̀ràn, Ọlọ́run AlágbáraBaba ayérayé, Ọmọ ọba aládé Àlàáfíà.

Ka pipe ipin Àìsáyà 9