Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àìsáyà 8:2-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

2. Èmi yóò sì pe Hùráyà, Àlùfáà àti Ṣekaráyà ọmọ Jébérékíà gẹ́gẹ́ bí ẹlẹ́rìí tí ó ṣeé gbọ́kànlé fún mi.

3. Lẹ́yìn náà, mo lọ sí ọ̀dọ̀ wòlíì-obìnrin náà, ó sì lóyún, ó sì bí ọmọkùnrin kan. Olúwa sì wí fún mi pé, “pe orúkọ rẹ̀ ní Maha-Ṣalali-Haṣi-Baṣì.

4. Kí ọmọkùnrin náà tó mọ bí a ti ń sọ pé ‘Baba mi’ tàbí ‘Ìyá mi’ gbogbo ọrọ̀ Dámásíkù àti ìkógun ti Ṣamáríà ni ọba àwọn Áṣíríà yóò ti kó lọ.”

5. Olúwa sì tún sọ fún mi pé:

6. Nítorí pé àwọn ènìyàn ti kọomi Ṣílóà tí ń ṣàn jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́tí wọ́n sì láyọ̀ lórí Réṣínìàti ọmọ Rẹ̀málíà,

7. fún ìdí èyí, Olúwa fẹ́ mú wá sóríi wọnagbára ìkún omi odòọba Ásíríà àti ògo rẹ̀yóò sì bo gbogbo àyasíi rẹ̀gbogbo bèbè di bíbò mọ́lẹ̀

8. yóò sì gbá rìẹrìẹ dé Júdà, a gba orí ẹ̀ lọ,yóò gba ibẹ̀ lọ yóò sì mú un dọ́run.Ìyẹ́ apá rẹ̀ tí ó nà yóò bo gbogbo ìbú ilẹ̀ náàÌwọ Ìmánúẹ́lì.

9. Ké ariwo ogun, ẹ̀yin orílẹ̀-èdè, kí a sì fọ́ọ yín túútúúú,fetísílẹ̀, ẹ̀yin ilẹ̀ jínjìn réré.Ẹ palẹ̀mọ́ fún ogun, kí a sì fọ́ ọ túútúúú!

10. Ẹ hun ète yín, yóò di títúká.Ẹ gbérò ètò náà, ṣùgbọ́n kì yóò dúró,nítorí Ọlọ́run wà pẹ̀lúu wa.

Ka pipe ipin Àìsáyà 8