Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àìsáyà 8:11-20 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

11. Olúwa bá mi sọ̀rọ̀ pẹ̀lú ọwọ́ agbára rẹ̀ lórí mi pẹ̀lú ìkìlọ̀ fún mi pé, èmi kò gbọdọ̀ tẹ̀lé ọ̀nà àwọn ènìyàn wọ̀nyí. Ó wí pé:

12. “Má ṣe pe éyí ní ọ̀tẹ̀ohun gbogbo tí àwọn ènìyàn wọ̀nyí bá pè ní ọ̀tẹ̀,má ṣe bẹ̀rù ohun tí wọ́n bá bẹ̀rù,má sì ṣe fòyà rẹ̀.

13. Olúwa àwọn ọmọ-ogun ni Ẹni tí ìwọ yóò kà sí mímọ́,Òun ni kí o bẹ̀rùÒun ni kí àyà rẹ̀ fò ọ́,

14. Òun yóò sì jẹ́ ibi mímọ́ṣùgbọ́n fún ilé Ísírẹ́lì méjèèjì ni yóò jẹ́, òkúta tí í mú ni kọṣẹ̀àti àpáta tí ó mú wọn ṣubúàti fún àwọn ènìyàn Jérúsálẹ́mù ni yóò jẹ́ tàkúté àti ẹ̀bìtì.

15. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ wọn ni yóò kọṣẹ̀,wọn yóò ṣubú wọn yóò sì fọ́ yángá,okùn yóò mú wọn, ọwọ́ yóò sì tẹ̀ wọ́n.”

16. Di májẹ̀mú náàkí o sì fi èdìdì di òfin náà láàrin àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mi.

17. Èmi yóò dúró de Olúwa,ẹni tí ó ń fi ojú rẹ̀ pamọ́ fún ilé Jákọ́bù.Mo fi ìgbẹ́kẹ̀lé mi sínú rẹ.

18. Èmi nìyí, àti àwọn ọmọ tí Olúwa fi fún mi. Àwa jẹ́ àmì àti àpẹẹrẹ ní Ísírẹ́lì láti ọ̀dọ̀ Olúwa àwọn ọmọ-ogun, ẹni tí ó ń gbé ní òké Síhónì.

19. Nígbà tí àwọn ènìyàn bá sọ fún un yín pé kí ẹ lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn abókúsọ̀rọ̀ àti àwọn Oṣó, ti máa ń kún tí wọ́n sì ń sọ̀rọ̀ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́, ǹjẹ́ kò ha yẹ kí àwọn ènìyàn béèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run wọn bí? Èéṣe tí ẹ fi ń bá òkú sọ̀rọ̀ ní orúkọ alààyè?

20. Sí òfin àti májẹ̀mú! Bí wọn kò bá sọ̀rọ̀ gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ yìí, wọn kò ní ìmọ́lẹ̀ ọjọ́.

Ka pipe ipin Àìsáyà 8