Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àìsáyà 8:10-16 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

10. Ẹ hun ète yín, yóò di títúká.Ẹ gbérò ètò náà, ṣùgbọ́n kì yóò dúró,nítorí Ọlọ́run wà pẹ̀lúu wa.

11. Olúwa bá mi sọ̀rọ̀ pẹ̀lú ọwọ́ agbára rẹ̀ lórí mi pẹ̀lú ìkìlọ̀ fún mi pé, èmi kò gbọdọ̀ tẹ̀lé ọ̀nà àwọn ènìyàn wọ̀nyí. Ó wí pé:

12. “Má ṣe pe éyí ní ọ̀tẹ̀ohun gbogbo tí àwọn ènìyàn wọ̀nyí bá pè ní ọ̀tẹ̀,má ṣe bẹ̀rù ohun tí wọ́n bá bẹ̀rù,má sì ṣe fòyà rẹ̀.

13. Olúwa àwọn ọmọ-ogun ni Ẹni tí ìwọ yóò kà sí mímọ́,Òun ni kí o bẹ̀rùÒun ni kí àyà rẹ̀ fò ọ́,

14. Òun yóò sì jẹ́ ibi mímọ́ṣùgbọ́n fún ilé Ísírẹ́lì méjèèjì ni yóò jẹ́, òkúta tí í mú ni kọṣẹ̀àti àpáta tí ó mú wọn ṣubúàti fún àwọn ènìyàn Jérúsálẹ́mù ni yóò jẹ́ tàkúté àti ẹ̀bìtì.

15. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ wọn ni yóò kọṣẹ̀,wọn yóò ṣubú wọn yóò sì fọ́ yángá,okùn yóò mú wọn, ọwọ́ yóò sì tẹ̀ wọ́n.”

16. Di májẹ̀mú náàkí o sì fi èdìdì di òfin náà láàrin àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mi.

Ka pipe ipin Àìsáyà 8