Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àìsáyà 7:7-16 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

7. Ṣíbẹ̀ èyí ni ohun tí Olúwa Àwọn ọmọ ogun wí:“ ‘Èyí kò ní wáyéÈyí kò le ṣẹlẹ̀,

8. nítorí Dámásíkù ni orí Árámù,orí Dámásíkù sì ni Résínì.Láàrin ọdún márùnlélọ́gọ́taÉfáímù yóò ti fọ́ tí kì yóò le jẹ́ ènìyàn mọ́.

9. Ṣamaríà ni orí fún Éfáímù,ẹni tí ó sì jẹ́ orí Samaríà náà ni ọmọ Rèmálíà.’ ”

10. Bákan náà Olúwa tún bá Áhásì sọ̀rọ̀,

11. “Béèrè fún ààmì lọ́wọ́ Olúwa Ọlọ́run rẹ, bóyá ní ọ̀gbun tí ó jìn jùlọ tàbí àwọn òkè tí ó ga jùlọ”

12. Ṣùgbọ́n Áhásì sọ pé, “Èmi kì yóò béèrè; Èmi kò ní dán Olúwa wò.”

13. Lẹ́yìn náà Àìṣáyà sọ pé, “Gbọ́ ní ìsinsìnyí, ìwọ ilé Dáfídì, kò ha tọ́ láti tan ènìyàn ní ṣùúrù, o ó ha tan Ọlọ́run ní ṣùúrù bí?

14. Nítorí náà, Olúwa fúnra ara rẹ̀ ni yóò fún ọ ní àmì kan. Wúndíá kan yóò lóyún, yóò sì bí ọmọkùnrin kan, yóò sì pe orúkọ rẹ̀ ní Ìmánúẹ́lì.

15. Òun yóò jẹ wàrà àti oyin nígbà tí ó bá ní ìmọ̀ tó láti kọ ẹ̀bi àti láti yan àre.

16. Ṣùgbọ́n kí ọ̀dọ́mọkùnrin náà tó mọ bí a ti ń kọ ẹ̀bi àti láti yan àre, ilẹ̀ àwọn ọba méjèèjì tí ń bà ọ́ lẹ́rù wọ̀nyí yóò ti di ahoro.

Ka pipe ipin Àìsáyà 7