Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àìsáyà 65:8-18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

8. Ohun tí Olúwa wí nìyìí:“Gẹ́gẹ́ bí ìgbà tí òjé sì tún wà nínú àpólà gírépùtí àwọn ènìyàn sì wí pé, ‘má ṣe bà á jẹ́,ohun dáradára sì kù sínú rẹ̀,’bẹ́ẹ̀ ni èmi yóò ṣe nítorí ìránṣẹ́ mi;Èmi kì yóò pa gbogbo wọn run.

9. Èmi yóò mú ìrandíran wá láti ìdílé Jákọ́bù,àti láti Júdà àwọn tí yóò jogún òkè ńlá mi wọ̀n ọn nì;àwọn àyànfẹ́ ènìyàn mi yóò jogún wọn,ibẹ̀ ni àwọn ìránṣẹ́ mi yóò sì gbé.

10. Ṣárónì yóò di pápá oko fún ọ̀wọ́ ẹran,àti àfonífojì Ákò yóò di ibi ìsinmi fún agbo ẹran,fún àwọn ènìyàn mi tí ó wá mi.

11. “Ṣùgbọ́n fún ẹ̀yin tí ó kọ Olúwa sílẹ̀tí ẹ sì gbàgbé òkè mímọ́ mi,tí ó tẹ́ tábìlì fún ọrọ̀tí ẹ sì kún abọ́ pẹ̀lú ọtí wáìnì fún àtubọ̀tán,

12. Èmi yóò yà ọ́ ṣọ́tọ̀ fún idà,àti pé ẹ̀yin yóò bẹ̀rẹ̀ mọ́lẹ̀ fún àwọn tí a pa;nítorí mo pè, ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò dáhùn.Mo ṣọ̀rọ̀ ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò tẹ́tísílẹ̀Ẹ̀yin ṣe búrurú ní ojú miẹ sì yan ohun tí ó bàmí lọ́kàn jẹ́.”

13. Nítorí náà ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí nìyìí:“Àwọn ìránṣẹ́ mi yóò jẹun;ṣùgbọ́n ebi yóò máa pa ẹ̀yin,àwọn ìránṣẹ́ mi yóò mu,ṣùgbọ́n òrùngbẹ yóò máa gbẹ ẹ̀yin;àwọn ìránṣẹ́ mi yóò ṣe àjọyọ̀,ṣùgbọ́n a ó dójú ti ẹ̀yin.

14. Àwọn ìránṣẹ́ mi yóò kọrinláti inú ayọ̀ ọkàn wọn wá,ṣùgbọ́n ẹ̀yin yóò kígbe sókèláti inú ìrora ọkàn yínàti ìpohùnréré ní ìròbìnújẹ́ ọkàn.

15. Ẹ̀yin yóò fi orúkọ yín sílẹ̀fún àwọn àyànfẹ́ mi gẹ́gẹ́ bí ègún; Olúwa àwọn ọmọ-ogun yóò sì pa yín,ṣùgbọ́n fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ni òunyóò fún ní orúkọ mìíràn

16. Ẹnikẹ́ni tí ó bá gbàdúrà ìbùkún ní ilẹ̀ náàyóò ṣe é nípaṣẹ̀ Ọlọ́run òtítọ́;Ẹni tí ó bá búra ní ilẹ̀ náàyóò búra nípaṣẹ̀ Ọlọ́run òtítọ́.Nítorí ìyọnu àtijọ́ yóò di ìgbàgbéyóò sì farasin kúrò lójú mi.

17. “Kíyèsí i, Èmi yóò dáàwọn ọ̀run tuntun àti ayé tuntunA kì yóò rántí ohun àtẹ̀yìnwá mọ́,tàbí kí wọn wá sí ọkàn.

18. Ṣùgbọ́n ẹ yọ̀ kí inú yín dùn títí láénínú ohun tí èmi yóò dá,nítorí èmi yóò dá Jérúsálẹ́mù láti jẹ́ ohun ìdùnnúàti àwọn ènìyàn rẹ̀, ohun ayọ̀.

Ka pipe ipin Àìsáyà 65