Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àìsáyà 65:1-5 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. “Èmi fi ara mi hàn fún àwọn tí kò béèrè fún mi;Àwọn tí kò wá mi ni wọ́n rí mi.Sí àwọn orílẹ̀ èdè tí kò pe orúkọ mi,Ni èmi wí pé, ‘Èmi nìyìí, Èmi nìyìí.’

2. Gbogbo ọjọ́ ni mo ti nawọ́ mi sítasí àwọn ènìyàn ọlọ́rùn líle,tí wọn ń rìn lọ́nà tí kò dára,tí wọ́n sì gbáralé èrò ara wọn

3. àwọn ènìyàn tí wọ́n bí mi nínú nígbà gbogbolójú ara mi gan an,wọ́n ń rúbọ nínú ọgbàwọ́n sì ń ṣun tùràrí lóríi pẹpẹ bíríkì;

4. wọ́n ń jókòó láàrin ibojìwọ́n sì ń lo òru wọn nínú ìṣọ́ ìkọ̀kọ̀;tí wọ́n ń jẹ ẹran ẹlẹ́dẹ̀,tí ìkòkò ọbẹ̀ wọn kún fún ẹran àìmọ́;

5. tí ó wí pé, ‘Ẹ sún mẹ́yìn; ẹ má wá sọ́dọ̀ mi,nítorí mo ti jẹ́ mímọ́ jù fún un yín!’Àwọn ènìyàn bẹ́ẹ̀ jẹ́ èéfín nínú ihò imú miiná tí ń fi gbogbo ọjọ́ jó.

Ka pipe ipin Àìsáyà 65