Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àìsáyà 64:1-4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ìwọ ìbá fa ọ̀run ya kí o sì ṣọ̀kalẹ̀ wá,tí àwọn òkè ńlá yóò fi wárìrì níwájú rẹ!

2. Gẹ́gẹ́ bí ìgbà tí iná mú ẹ̀ka igi jótí ó sì mú kí omi ó hó,ṣọ̀kalẹ̀ wá kí orúkọ rẹ le di mímọ̀ fún àwọn ọ̀ta rẹkí o sì jẹ́ kí àwọn orílẹ̀ èdè kí ó wárìrì níwájú rẹ!

3. Nítorí nígbà tí o bá ṣe àwọn ohun ẹ̀rù tí àwa kò nírètí,o sọ̀kalẹ̀ wá, àwọn òkè ńlá sì wárìrì níwájú rẹ.

4. Láti ìgbà ìwásẹ̀ kò sí ẹni tí ó gbọ́ ríkò sí etí kan tí ó gbọ́ ọ,kò sí ojú tí ó tí ì rí Ọlọ́run mìíràn lẹ́yìn rẹ,tí ó máa ń ṣe nǹkan lórúkọ àwọn tí ó dúró dè é.

Ka pipe ipin Àìsáyà 64