Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àìsáyà 63:7-12 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

7. Èmi yóò sọ nípa àánú Olúwaìṣe rẹ gbogbo tí ó yẹ kí a yìn ín fún,gẹ́gẹ́ bí ohun tí Olúwa ti ṣe fún wabẹ́ẹ̀ ni, ohun rere gbogbo tí ó ti ṣefún ilé Ísírẹ́lìgẹ́gẹ́ bí àánú àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ oore rẹ̀.

8. Ó wí pé, “Lótítọ́ ènìyàn mi ni wọ́n,àwọn ọmọ tí kì yóò jẹ́ òpùrọ́ fún mi”;bẹ́ẹ̀ ni, ó sì di Olùgbàlà wọn.

9. Nínú un gbogbo ìpọ́njúu wọn, inú òun pẹ̀lú bàjẹ́àti ańgẹ́lì tí ó wà níwájú rẹ̀ gbà wọ́n là.Nínú Ìfẹ́ àti àánú rẹ̀, ó rà wọ́n padà;ó gbé wọn ṣókè ó sì pọ̀n wọ́nní gbogbo ọjọ́ ìgbà n nì.

10. Ṣíbẹ̀ṣíbẹ̀ wọ́n ṣọ̀tẹ̀wọ́n sì ba Ẹ̀mí Mímọ́ rẹ̀ nínú jẹ́.Bẹ́ẹ̀ ni ó yípadà ó sì di ọ̀ta wọnòun tìkálára rẹ̀ sì bá wọn jà.

11. Lẹ́yìn náà ni àwọn ènìyàn rẹ̀ rántí ọjọ́ ìgbà n nì,àwọn ọjọ́ Mósè àti àwọn ènìyàn rẹ̀níbo ni ẹni náà wà tí ó mú wọn la òkun já,pẹ̀lú olùṣọ́ àgùntàn agbo ẹran rẹ̀?Níbo ni ẹni náà wà tí ó ránẸ̀mí Mímọ́ rẹ̀ sáàrin wọn,

12. ta ni ó rán ògo apá ti agbára rẹ̀láti wà ní apá ọ̀tún Mósè,ta ni ó pín omi níyà níwájú wọn,láti gba òkìkí ayérayé fún ara rẹ̀,

Ka pipe ipin Àìsáyà 63