Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àìsáyà 63:12-19 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

12. ta ni ó rán ògo apá ti agbára rẹ̀láti wà ní apá ọ̀tún Mósè,ta ni ó pín omi níyà níwájú wọn,láti gba òkìkí ayérayé fún ara rẹ̀,

13. ta ni ó ṣíwájú wọn la àwọn ọ̀gbun nì já?Gẹ́gẹ́ bí ẹṣin ni gbangba ìlú wọn tí kò sì kọṣẹ̀;

14. gẹ́gẹ́ bí ọ̀wọ́ ẹran tí ó lọ sí pápá oko,a fún wọn ní ìsinmi láti ọwọ́ Ẹ̀mí Olúwa.Báyìí ni ẹ ṣe tọ́ àwọn ènìyàn yínláti fún ara yín ní orúkọ kan tí ó lógo.

15. Bojúwolẹ̀ láti ọ̀run kí o sì rí iláti ìtẹ́ ògo rẹ, mímọ́ àti ológo.Níbo ni ipá àti agbára rẹ wà?Ìwà jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́ rẹ àti àánú rẹ ni atí mú kúrò níwájúu wa.

16. Ṣùgbọ́n ìwọ ni Baba wa,bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Ábúráhámù kò mọ̀ wátàbí Ísírẹ́lì mọ ẹni tí à á ṣe;ìwọ, Olúwa ni Baba wa,Olùràpadà wa láti ìgbà n nì ni orúkọ rẹ.

17. Èéṣe Olúwa tí o fi jẹ́ kí a ṣáko kúrò ní ojú ọ̀nà rẹtí o sì ṣé àyà wa le tó bẹ́ẹ̀ tí àwa kò fi bọ̀wọ̀ fún ọ?Padà nítorí àwọn ìránṣẹ́ rẹ,àwọn ẹ̀yà tíi ṣe ogún ìní rẹ.

18. Fún ìgbà díẹ̀ ni àwọn ènìyàn rẹ fi gba ibi mímọ́ rẹ,ṣùgbọ́n nísinsìn yìí àwọn ọ̀tá wa ti tẹ ibi mímọ́ rẹ mọ́lẹ̀.

19. Àwa jẹ́ tìrẹ láti ìgbà n nì;ṣùgbọ́n ìwọ kò tí ì jọba lé wọn lórí,a kò sì tí ì pè wọ́n mọ́ orúkọ rẹ.

Ka pipe ipin Àìsáyà 63