Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àìsáyà 62:1-6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Nítorí Ṣíhónì èmi kì yóò dákẹ́,nítorí i Jérúsálẹ́mù èmi kì yóò sinmi ẹnu,títí tí òdodo rẹ̀ yóò fi tàn bí òwúrọ̀,àti ìgbàlà rẹ̀ bí i tọ́ọ̀sì tí ń jó geregere.

2. Àwọn orílẹ̀ èdè yóò rí òdodo rẹ,àti gbogbo ọba ògo rẹa ó sì máa pè ọ́ ní orúkọ mìírànèyí tí ẹnu Olúwa yóò fi fún un.

3. Ìwọ yóò sì jẹ́ adé dídán ní ọwọ́ Olúwa,adé ọba ní ọwọ́ Ọlọ́run rẹ.

4. Wọn kì yóò pè ọ́ ní ìkọ̀sílẹ̀ mọ́tàbí kí wọ́n pe ilẹ̀ rẹ ní ahoro.Ṣùgbọ́n a ó máa pè ọ́ ní Hẹfísíbà,àti ilẹ̀ rẹ ní Béúlà;nítorí Olúwa yóò yọ́nú sí ọàti ilẹ̀ rẹ ni a ó gbé níyàwó.

5. Gẹ́gẹ́ bí ọ̀dọ́mọkùrin tí í gbé ọ̀dọ́mọbìnrin níyàwóbẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọkùnrin rẹ yóò gbé ọ níyàwóGẹ́gẹ́ bí ọkọ ìyàwó ṣe é yọ̀ lórí ìyàwó rẹ̀,bẹ́ẹ̀ ni Ọlọ́run rẹ yóò yọ̀ lóríì rẹ.

6. Èmi ti fi olùṣọ́ ránṣẹ́ sórí odi rẹ ìwọ Jérúsálẹ́mù;wọn kì yóò lè dákẹ́ tọ̀sán tòru.Ẹ̀yin tí ń ké pe Olúwa,ẹ má ṣe fún ra yín ní ìsinmi,

Ka pipe ipin Àìsáyà 62