Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àìsáyà 60:13-17 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

13. “Ògo Lẹ́bánónì yóò wá sí ọ̀dọ̀ rẹ,igi páínì, fírì àti ṣípírẹ́sì papọ̀,láti bu ọlá fún ilé ìsìn mi;àti pé èmi yóò sì ṣe ibi ẹsẹ̀ mi lógo.

14. Àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin àwọn apọ́nilójú rẹ yóòwá foríbalẹ̀ fún ọ;gbogbo àwọn tí ó ti kẹ́gàn rẹ ni wọn yóò tẹríba níwájú rẹwọn yóò sì pè ọ́ ní Ìlú Olúwa,Ṣíhónì ti Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì.

15. “Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a ti kóríra rẹ, a sì kọ̀ ọ́ sílẹ̀,láìsí ẹnìkan tí ó ń gba ọ̀dọ̀ rẹ kọjá,Èmi yóò ṣe ọ́ ní ìṣògo ayérayéàti ayọ̀ àtìrandíran.

16. Ìwọ yóò mu wàrà gbogbo orílẹ̀ èdèa ó sì rẹ̀ ọ́ ni ọmú àwọn ayaba.Nígbà náà ni ìwọ yóò mọ̀ pé Èmi Olúwa,èmi ni Olùgbàlà rẹ,Olùdáǹdè rẹ, Alágbára ti Jákọ́bù Nnì.

17. Dípò búróǹsì, èmi ó mú wúrà wá fún ọ,àti fàdákà dípò irun Dípò igi yóò mú búróńsì wá,àti irun dípò òkúta.Èmi yóò fi àlàáfíà ṣe gómínà rẹàti òdodo gẹ́gẹ́ bí alákòóso rẹ.

Ka pipe ipin Àìsáyà 60