Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àìsáyà 58:6-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

6. “Ǹjẹ́ irú ààwẹ̀ tí mo ti yàn kọ́ ni èyí:láti já gbogbo ẹ̀wọ̀n àìsòdodoàti láti tú gbogbo okùn àjàgà,láti tú gbogbo àwọn ti à ń ni lára sílẹ̀àti láti fọ́ gbogbo àjàgà?

7. Kì í ha á ṣe láti pín oúnjẹ yín fún àwọn tí ebi ń paàti láti pèsè ibùgbé fún àwọn òtòsì tí ń rìn káàkirinígbà tí ẹ bá rí ẹni tí ó wà níhòòhò, láti daṣọ bò ó,àti láti má ṣe lé àwọn ẹ̀jẹ̀ àti ẹran yín sẹ́yìn?

8. Nígbà náà ni ìmọ́lẹ̀ rẹ yóò tàn jáde bí òwúrọ̀àti ìmúláradá rẹ yóò farahàn kíákíá;nígbà náà ni òdodo rẹ yóò sì lọ níwájúù rẹ,ògo Olúwa yóò sì jẹ́ ààbò lẹ́yìn rẹ.

9. Nígbà yìí ni ẹ̀yin yóò pè, tí Olúwa yóò sì dáhùn;ẹ̀yin yóò kígbe fún ìrànlọ́wọ́, òun yóò sì wí pé: Èmi nìyí.“Bí ẹ̀yin bá mú àjàgà aninilára kúrò,pẹ̀lú ìka àléébù nínà àti ọ̀rọ̀ ìṣáátá,

10. àti bí ẹ̀yin bá ná ara yín bí owó nítorí àwọn tí ebi ń patí ẹ sì tẹ́ ìfẹ́ àwọn tí à ń ni lára lọ́rùn,nígbà náà ni ìmọ́lẹ̀ yín yóò ràn nínú òkùnkùn,àti òru yín yóò dàbí ọ̀ṣán-gangan.

11. Olúwa yóò máa tọ́ ọ yín nígbà gbogbo;òun yóò tẹ́ gbogbo àìní ìn yín lọ́rùn ní ilẹ̀ tí òòrùn ń tan ìmọ́lẹ̀yóò sì fún egungun rẹ lókun.Ìwọ yóò sì dàbí ọgbà tí a bomirin dáadáa,àti bí orísun tí omi rẹ̀ kì í tán.

Ka pipe ipin Àìsáyà 58