Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àìsáyà 57:14-21 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

14. A ó sì sọ wí pé:“Tún mọ, tún mọ, tún ọ̀nà náà ṣe!Ẹ mú àwọn ohun ìkọ̀ṣẹ̀ kúrò ní ọ̀nà àwọn ènìyàn mi.”

15. Nítorí èyí ni ohun tí Ẹni gíga àti ọlọ́lá jùlọ wíẹni tí ó wà títí láé, tí orúkọ rẹ̀ jẹ́ mímọ́:“Mo ń gbé ní ibi gíga àti ibi mímọ́,ṣùgbọ́n pẹ̀lú ẹni n nì tí ó ní ìròbìnújẹ́ àti ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀,láti sọ ẹ̀mí onírẹ̀lẹ̀ náà jíàti láti sọ ẹ̀mí oníròbìnújẹ́ n nì jí.

16. Èmi kì yóò fẹ̀ṣùn kan ni títí láé,tàbí kí n máa bínú ṣá á,nítorí nígbà náà ni ọkàn ọmọnìyàn yóòrẹ̀wẹ̀sì níwájú mièémí ọmọnìyàn tí mo ti dá.

17. Inú bí mi nítorí ẹ̀ṣẹ̀ ọ̀kánjúà rẹ̀;mo fìyà jẹ ẹ́, mo sì fojúù mi pamọ́ ní ìbínúṣíbẹ̀, ó tẹ̀ṣíwájú nínú tinú-mi-ni-n ó ṣe ọ̀nà rẹ̀.

18. Èmi ti rí ọ̀nà rẹ̀ gbogbo, ṣùgbọ́n Èmi yóò wò ó sàn;Èmi yóò tọ́ ọ sọ́nà n ó sì mú ìtùnú tọ̀ ọ́ wá,

19. ní dídá ìyìn sí ètè àwọn tí ń ṣọ̀fọ̀ ní Ísírẹ́lì.Àlàáfíà, àlàáfíà fún àwọn tí ó wà lókèèrè àti nítòsí,”ni Olúwa wí, “Àti pé Èmi yóò wo wọ́n sàn.”

20. Ṣùgbọ́n àwọn ìkà dàbí i ríru òkuntí kò le è sinmi,tí ìgbì rẹ̀ ń rú pẹ̀tẹ̀pẹ́tẹ̀ àti ẹrọ̀fọ̀ sókè.

21. “Kò sí àlàáfíà,” ni Ọlọ́run mi wí, “fún àwọn ìkà.”

Ka pipe ipin Àìsáyà 57