Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àìsáyà 53:4-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

4. Lótìítọ́ ó ti ru àìlera wa lọó sì ti ru ìbànújẹ́ wa pẹ̀lú,ṣíbẹ̀ a kà á sí ẹni tí Ọlọ́run lù,tí ó lù, tí a sì pọ́n lójú.

5. Ṣùgbọ́n a ṣá a lọ́gbẹ́ nítorí àìṣedédé waa pa á lára nítorí àìsòdodo wa;ìjìyà tí ó mú àlàáfíà wá fún wa wà lóríi rẹ̀,àti nípa ọgbẹ́ rẹ̀ ni a fi múwa láradá.

6. Gbogbo wa bí àgùntàn, ti sìnà lọ,ẹnìkọ̀ọ̀kan wa ti yà sí ọ̀nà ara rẹ̀; Olúwa sì ti gbé e ka orí ara rẹ̀gbogbo àìṣedédé wa.

7. A jẹ ẹ́ níyà, a sì pọ́n ọn lójú,ṣíbẹ̀ kò ya ẹnu rẹ̀;a mú un wá gẹ́gẹ́ bí ọ̀dọ́-àgùntàn sọ́dọ̀ alápatà,àti gẹ́gẹ́ bí àgùntàn tí ó dákẹ́ níwájú olùrẹ́run rẹ̀,ṣíbẹ̀ kò ya ẹnu rẹ̀.

8. Pẹ̀lú ìpọ́nlójú àti ìdánilẹ́jọ́ ni a mú un jáde lọ,ta ni ó sì le sọ nípa ìrànlọ́wọ́ rẹ̀?Nítorí a ké e kúrò ní ilẹ̀ àwọn alààyè;nítorí àìṣedédé àwọn ènìyàn mi ni a ṣe lù ú.

9. A fún un ní ibojì pẹ̀lú àwọn ìkà,àti pẹ̀lú àwọn ọlọ́rọ̀ ní ikú rẹ̀,bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò hùwà jàgídíjàgan kan,tàbí kí a rí ẹ̀tàn kan ní ẹnu rẹ̀.

10. Ṣíbẹ̀, ó wu Olúwa láti pa á láraàti láti mú kí ó jìyà,bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Olúwa fi ayé rẹ̀fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀,Òun yóò rí àrọ́mọdọ́mọ rẹ̀ àti ọjọ́ ayérẹ̀ yóò pẹ́ títí,àti ète Olúwa ni yóò gbèrú ní ọwọ́ rẹ̀.

Ka pipe ipin Àìsáyà 53