Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àìsáyà 53:1-8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ta ni ó ti gba ìhìn in wa gbọ́àti ta ni a ti fi apá Olúwa hàn fún?

2. Òun dàgbà ṣókè níwájúu rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àṣẹ̀ṣẹ̀yọ èhù,àti gẹ́gẹ́ bí i gbòngbo tí ó jáde láti inú ìyàngbẹ ilẹ̀.Òun kò ní ẹwà tàbí ògo láti fàwá sọ́dọ̀ ara rẹ̀,kò sí ohun kankan nínú àbùdá rẹ̀tí ó fi yẹ kí a ṣàfẹ́ríi rẹ̀.

3. A kẹ́gàn rẹ̀ àwọn ènìyàn sì kọ̀ ọ́ sílẹ̀,ẹni ìbànújẹ́, tí ó sì mọ bí ìpọ́njú ti rí.Gẹ́gẹ́ bí ẹnìkan tí àwọn ènìyàn ń fojú pamọ́ fúna kẹ́gàn rẹ, a kò sì bọlá fún un rárá.

4. Lótìítọ́ ó ti ru àìlera wa lọó sì ti ru ìbànújẹ́ wa pẹ̀lú,ṣíbẹ̀ a kà á sí ẹni tí Ọlọ́run lù,tí ó lù, tí a sì pọ́n lójú.

5. Ṣùgbọ́n a ṣá a lọ́gbẹ́ nítorí àìṣedédé waa pa á lára nítorí àìsòdodo wa;ìjìyà tí ó mú àlàáfíà wá fún wa wà lóríi rẹ̀,àti nípa ọgbẹ́ rẹ̀ ni a fi múwa láradá.

6. Gbogbo wa bí àgùntàn, ti sìnà lọ,ẹnìkọ̀ọ̀kan wa ti yà sí ọ̀nà ara rẹ̀; Olúwa sì ti gbé e ka orí ara rẹ̀gbogbo àìṣedédé wa.

7. A jẹ ẹ́ níyà, a sì pọ́n ọn lójú,ṣíbẹ̀ kò ya ẹnu rẹ̀;a mú un wá gẹ́gẹ́ bí ọ̀dọ́-àgùntàn sọ́dọ̀ alápatà,àti gẹ́gẹ́ bí àgùntàn tí ó dákẹ́ níwájú olùrẹ́run rẹ̀,ṣíbẹ̀ kò ya ẹnu rẹ̀.

8. Pẹ̀lú ìpọ́nlójú àti ìdánilẹ́jọ́ ni a mú un jáde lọ,ta ni ó sì le sọ nípa ìrànlọ́wọ́ rẹ̀?Nítorí a ké e kúrò ní ilẹ̀ àwọn alààyè;nítorí àìṣedédé àwọn ènìyàn mi ni a ṣe lù ú.

Ka pipe ipin Àìsáyà 53