Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àìsáyà 51:18-23 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

18. Nínú gbogbo ọmọ tí ó bíkò sí ọ̀kankan tí ó lè tọ́ ọ sọ́nànínú gbogbo ọmọ tí ó tọ́kò sí èyí tí ó le fà á lọ́wọ́.

19. Àjálù ìlọ́po ìlọ́po yìí ti dé bá ọ—ta ni yóò tù ọ́ nínú?Ìparun àti Ìdahoro, ìyàn àti idàta ni yó pẹ̀tù sí ọ lọ́kàn?

20. Àwọn ọmọkùnrin rẹ ti dákú;wọ́n sùn sí oríta gbogbo òpópónà,gẹ́gẹ́ bí ẹtu tí a dé mọ́nú àwọ̀n.Ìbínú Olúwa ti kún inú un wọn fọ́fọ́ọ́fọ́àti ìbáwí Ọlọ́run yín.

21. Nítorí náà ẹ gbọ́ èyí, ẹ̀yin tí a ti ṣẹ́ níṣẹ̀ẹ́,tí ọtí ń pa, ṣùgbọ́n kì í ṣe fún wáìnì

22. Ohun tí Olúwa yín Alágbára jùlọ wí nìyìí,Ọlọ́run rẹ, ẹni tí ó ń pa ènìyàn an rẹ̀ mọ́“Kíyèsí i, mo ti mú un kúrò ní ọwọ́ọ̀ rẹkọ́ọ̀bù tí ó mú ọ ta gbọ̀ngbọ̀nọ́n;láti inú kọ́ọ̀bù náà, ẹ̀kan ìbínú mi,ni ìwọ kì yóò mu mọ́.

23. Èmi yóò fi lé àwọn apọ́nnílójú rẹ lọ́wọ́,àwọn tí ó wí fún ọ pé,‘Dọ̀bálẹ̀, tó bẹ́ẹ̀ tí a ó fi máa rìn lóríì rẹ.’Ìwọ náà ṣe ẹ̀yìn rẹ gẹ́gẹ́ bí ilẹ̀gẹ́gẹ́ bí òpópónà láti máa rìn lóríi rẹ̀.”

Ka pipe ipin Àìsáyà 51