Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àìsáyà 51:15-22 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

15. Nítorí Èmi ni Olúwa Ọlọ́run rẹ,tí ó ń ru òkun ṣókè tó bẹ́ẹ̀ tíìgbì rẹ̀ fi ń pariwo Olúwa àwọn ọmọ-ogun ni orúkọ rẹ̀.

16. Mo ti fi ọ̀rọ̀ mi sí ẹnu rẹmo sì ti fi òjìji ọwọ́ mi bò ọ́Èmi tí mo tẹ́ àwọn ọ̀run sí àyè rẹ̀,ẹni tí ó fi ìpìlẹ̀ ilẹ̀ ayé lélẹ̀,àti ẹni tí ó sọ fún Ṣhíónì pé,‘Ẹ̀yin ni ènìyàn mi.’ ”

17. Jí, jí!Gbéra nílẹ̀ Ìwọ Jérúsálẹ́mù,ìwọ tí o ti mu láti ọwọ́ Olúwakọ́ọ̀bù ìbínú rẹ̀,ìwọ tí o ti fà á mu dégẹ̀dẹ̀gẹ́dẹ̀fèrè tí ó n mú kí ènìyàn ta gbọ̀ngbọ̀nọ́n.

18. Nínú gbogbo ọmọ tí ó bíkò sí ọ̀kankan tí ó lè tọ́ ọ sọ́nànínú gbogbo ọmọ tí ó tọ́kò sí èyí tí ó le fà á lọ́wọ́.

19. Àjálù ìlọ́po ìlọ́po yìí ti dé bá ọ—ta ni yóò tù ọ́ nínú?Ìparun àti Ìdahoro, ìyàn àti idàta ni yó pẹ̀tù sí ọ lọ́kàn?

20. Àwọn ọmọkùnrin rẹ ti dákú;wọ́n sùn sí oríta gbogbo òpópónà,gẹ́gẹ́ bí ẹtu tí a dé mọ́nú àwọ̀n.Ìbínú Olúwa ti kún inú un wọn fọ́fọ́ọ́fọ́àti ìbáwí Ọlọ́run yín.

21. Nítorí náà ẹ gbọ́ èyí, ẹ̀yin tí a ti ṣẹ́ níṣẹ̀ẹ́,tí ọtí ń pa, ṣùgbọ́n kì í ṣe fún wáìnì

22. Ohun tí Olúwa yín Alágbára jùlọ wí nìyìí,Ọlọ́run rẹ, ẹni tí ó ń pa ènìyàn an rẹ̀ mọ́“Kíyèsí i, mo ti mú un kúrò ní ọwọ́ọ̀ rẹkọ́ọ̀bù tí ó mú ọ ta gbọ̀ngbọ̀nọ́n;láti inú kọ́ọ̀bù náà, ẹ̀kan ìbínú mi,ni ìwọ kì yóò mu mọ́.

Ka pipe ipin Àìsáyà 51