Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àìsáyà 5:19-26 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

19. sí àwọn tí ó sọ pé, “Jẹ́ kí Ọlọ́run ṣe kíákíá,jẹ́ kí ó yára ṣiṣẹ́ rẹ̀ kí a lè ríi,jẹ́ kí ó súnmọ́ bíjẹ́ kí ètò ẹni mímọ́ Ísírẹ́lì kí ó dé,kí àwa kí ó le mọ̀ ọ́n.”

20. Ègbé ni fún àwọn tí ń pe ibi ní rere, àti rere ní ibi,tí ń fi òkùnkùn ṣe ìmọ́lẹ̀ àti ìmọ́lẹ̀ ṣe òkunkun,tí ń fi ìkorò ṣe adùn àti adùn ṣe ìkorò.

21. Ègbé ni fún àwọn tí ó gbọ́n lójú ara wọntí wọ́n já fáfá lójú ara wọn.

22. Ègbé ni fún àwọn akọni nínú wáìnì mímuàti àwọn akíkanjú nínú àdàlú ọtí,

23. tí wọ́n dá ẹlẹ́bi sílẹ̀ nítorí àbẹ̀tẹ́lẹ̀,tí wọn sì du aláre ní ẹ̀tọ́.

24. Nítorí náà, gẹ́gẹ́ bí ahọ́n iná ṣe ń jó àkékù koríko runàti bí koríko ṣe relẹ̀ wẹ̀sì nínú iná,bẹ́ẹ̀ ni egbò wọn yóò jẹràtí òdodo wọn yóò sì fẹ́ lọ bí eruku:nítorí pé wọ́n ti kọ òfin Olúwa àwọn ọmọ-ogun sílẹ̀wọ́n sì gan ọ̀rọ̀ Ẹni mímọ́ Ísírẹ́lì.

25. Nítorí náà, ìbínú Olúwa gbóná mọ́ àwọn ènìyàn rẹ̀,ó ti gbé ọwọ́ rẹ̀ ṣókè, ó sì lù wọ́n bolẹ̀.Àwọn òkè mì tìtì,àwọn òkú sì dàbí ààtàn lójú òpópó ọ̀nà.Pẹ̀lúu gbogbo èyí, ìbínú rẹ̀ kò tíí kúrò,ọ̀wọ́ rẹ̀ sì gbé ṣókè síbẹ̀.

26. Ó gbé ọ̀págun ṣókè sí àwọn orílẹ̀-èdè tí ó jìnnà-réré,Ó súfèé sí àwọn tí ó wà ní ìpẹ̀kun ilẹ̀.Àwọn rè é, wọ́n ti sáré

Ka pipe ipin Àìsáyà 5