Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àìsáyà 5:1-4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Èmi yóò kọrin fún ẹni tí mo fẹ́rànorin kan nípa ọgbà-àjàrà rẹ̀;Olùfẹ́ẹ̀ mi ní ọgbà-àjàrà kanní ẹ̀gbẹ́ òkè ẹlẹ́tù lójú.

2. Ó tu ilẹ̀ rẹ̀, ó ṣa òkúta ibẹ̀ kúròó sì gbin àyànfẹ́ àjàrà síi.Ó kọ́ ilé-ìṣọ́ sí inú un rẹ̀ó sì ṣe ìfúntí kan ṣíbẹ̀ pẹ̀lú.Lẹ́yìn náà, ó ń retí èso àjàrà dáradára,ṣùgbọn èṣo búburú ni ó ti ibẹ̀ wá.

3. “Ní ìsinsin yìí ẹ̀yín olùgbé Jérúsálẹ́mùàti ẹ̀yin ènìyàn Júdàẹ ṣe ìdájọ́ láàrin èmi àtiọgbà àjàrà mi.

4. Kín ni ó kù tí n ò bá tún ṣe sí ọgbà àjàrà mi.Ju èyí tí mo ti ṣe lọ?Nígbà tí mo ń wá èso dáradára,èéṣe tí ó fi ṣo kíkan?

Ka pipe ipin Àìsáyà 5