Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àìsáyà 48:5-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

5. Nítorí náà mo ti sọ nǹkan wọ̀nyí fún ọní ọjọ́ tí ó ti pẹ́;kí wọn ó tó ṣẹlẹ̀ mo ti kéde wọn fún un yíntó bẹ́ẹ̀ tí ìwọ kò fi lè sọ pé,‘Àwọn ère mi ló ṣe wọ́n;àwọn ère igi àti òrìṣà irin ló fọwọ́ sí i.’

6. Ìwọ ti gbọ́ àwọn nǹkan wọ̀nyí; wo gbogbo wọnǸjẹ́ o kò ní gbà wọ́n bí?“Láti ìsinsìnyìí lọ, Èmi yóò máa sọfún ọ nípa nǹkan tuntun,àwọn nǹkan tí ó farasin tí ìwọ kò mọ̀.

7. A dá wọn ní àkókò yìí kì í ṣe láti ìgbà pípẹ́ìwọ kò tí ì gbọ́ nípa wọn títí di òní.Nítorí náà, ìwọ kò lè sọ pé,‘Bẹ́ẹ̀ ni, mo mọ̀ nípa wọn.’

8. Ìwọ a ha ti gbọ́ tàbí ó ti yé ọ bíláti ìgbà àtijọ́ etí kò ti di yíyà.Ǹjẹ́ mo mọ̀ bí o ti jẹ́ alárékérekè tó;a ń pè ọ́ ní ọlọ̀tẹ̀ láti ìgbà ìbí rẹ.

9. Nítorí orúkọ ara mi, mo dáwọ́ ìbínú mi dúró;nítorí ìyìn ara mi, mo fà á ṣẹ́yìn kúrò lọ́dọ̀ rẹ,kí a má ba à ké ọ kúrò.

10. Wò ó, èmi ti tún ọ ṣe, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pékì í ṣe bí i fàdákà;Èmi ti dán ọ wò nínú ìléru ìpọ́njú.

11. Nítorí orúkọ mi, nítorí orúkọ mi, mo ṣe èyíBáwo ni mo ṣe lè jẹ́ kí a ba orúkọ mi jẹ́.Èmi kì yóò fi ògo mi fún ẹlòmìíràn.

12. “Tẹ́tí sí mi, Ìwọ Jákọ́bùÍsírẹ́lì ẹni tí mo pè:Èmi ni ẹni náà;Èmi ni ẹni àkọ́kọ́ àti ẹni ìgbẹ̀yìn.

13. Ọwọ́ mi pàápàá ni ó fi àwọn ìpìlẹ̀ ayé ṣọlẹ̀,àti ọwọ́ ọ̀tún mi ni ó tẹ àwọn ọ̀run;nígbà tí mo pè wọ́n,gbogbo wọn dìde ṣókè papọ̀.

14. “Ẹ gbárajọ pọ̀ gbogbo yín kí ẹ sì dẹtí:Èwo nínú àwọn ère òrìṣà rẹló ti sọ nǹkan wọ̀nyí?Àkójọpọ̀ àwọn àyànfẹ́ Olúwani yóò gbé ète yìí jáde sí Bábílónì;apá rẹ̀ ni yóò dojú kọ àwọn aráa Bábílónì.

Ka pipe ipin Àìsáyà 48