Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àìsáyà 47:1-8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. “Ṣọ̀kalẹ̀, jókòó nínú eruku,wúndíá ọmọbìnrin Bábílónì;jókòó ní ilẹ̀ẹ́lẹ̀ láìsí ìtẹ́,ọmọbìnrin àwọn ará Bábílónì.A kì yóò pè ọ́ ní aláìlókun àti ẹlẹgẹ́ mọ́.

2. Mú òkúta-ọlọ kí o sì lọ ìyẹ̀fun;mú ìbòjú ù rẹ kúrò.Ká yẹ̀rì rẹ sókè, kí o hó ẹṣẹ̀ rẹ sílẹ̀,kí o sì la inú odò lọ.

3. Ìhòòhò rẹ ni a ó fihàn sítaàti ìtìjú rẹ ni a ó sí sílẹ̀.Èmi yóò sì gba ẹ̀ṣan;Èmi kì yóò sì dá ẹnìkan sí.”

4. Olùràpadà wa Olúwa àwọn ọmọ-ogun ni orúkọ rẹ̀òun ni Ẹni-Mímọ́ Ísírẹ́lì.

5. “Jókòó ní ìdákẹ́jẹ́ẹ́, lọ sínú òkùnkùn,ọmọbìnrin àwọn ará Bábílónì;a kì yóò pè ọ́ ní ọbabìnrinàwọn ilẹ̀-ọba mọ́.

6. Inú bí mi sí àwọn ènìyàn mití mo sì ba ogún mi jẹ́;Mo fi wọ́n lé ọ lọ́wọ́,Ìwọ kò sì síjú àánú wò wọ́n.Lórí àwọn arúgbó pẹ̀lúní o gbé àjàgà tí ó wúwo lé.

7. Ìwọ wí pé, ‘Èmi yóò tẹ̀ṣíwájú títí láé—ọba-bìnrin ayérayé!’Ṣùgbọ́n ìwọ kò kíyèsí nǹkan wọ̀nyítàbí kí o ronú nípa ohun tí ó lè ṣẹlẹ̀.

8. “Nísinsìn yìí, tẹ́tísílẹ̀, ìwọ oníwọ̀ra ẹ̀dátí o kẹ̀tẹ̀ǹfẹ̀ nínú ààbò rẹtí o sì ń sọ fún ara rẹ pé,‘Èmi ni, kò sì sí ẹlòmìíràn lẹ́yìn mi.Èmi kì yóò di opótàbí kí n pàdánù àwọn ọmọ.’

Ka pipe ipin Àìsáyà 47