Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àìsáyà 45:3-16 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

3. Èmi yóò sì fún ọ ní àwọn ọrọ̀ ibi òkùnkùn,ọrọ̀ tí a kó pamọ́ sí àwọn ibi tí ó farasin,Tó bẹ́ẹ̀ tí ìwọ yóò fi mọ̀ pé Èmi ni Olúwa,Ọlọ́run Ísírẹ́lì, ẹni tí ó pè ọ́ pẹ̀lú orúkọ rẹ.

4. Nítorí Jákọ́bù ìránṣẹ́ miàti Ísírẹ́lì ẹni tí mo yànMo pè ọ́ pẹ̀lú orúkọ rẹ,mo sì gbé oyè kan kà ọ́ lóríbí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìwọ kò gbà mí.

5. Èmi ni Olúwa, àti pé kò sí ẹlòmìíràn;yàtọ̀ sí èmi kò sí ọlọ́run kan,Èmi yóò fún ọ ní okun,bí o kò tilẹ̀ tí ì gbà mí,

6. tí o fi jẹ́ pé láti ìlà oòrùntítí dé ibi ìwọ̀ rẹ̀kí ènìyàn le mọ̀, kò sí ẹnìkan lẹ́yìn mi.

7. Mo dá ìmọ́lẹ̀, mo sì dá òkùnkùnmo mú àlàáfíà wá, mo sì dá àjálù;Èmi Olúwa ni ó ṣe nǹkan wọ̀nyí.

8. “Ìwọ ọ̀run lókè rọ òjò òdodo sílẹ̀;jẹ́ kí àwọ̀sánmọ̀ kí ó rọ̀ ọ́ sílẹ̀.Jẹ́ kí ilẹ̀ kí ó yanu gbàgàdà,jẹ́ kí ìgbàlà kí ó dìde sókè,jẹ́ kí òdodo kí ó dàgbà pẹ̀lú rẹ̀;Èmi Olúwa ni ó ti dá a.

9. “Ègbé ni fún ènìyàn tí ó ń bá Ẹlẹ́dàá rẹ̀ jà,ẹni tí òun jẹ́ àpáàdì kan láàrin àwọn àpáàdì tí ó wà lórí ilẹ̀.Ǹjẹ́ amọ̀ lè sọ fún amọ̀kòkò, pé:‘Kí ni ohun tí ò ń ṣe?’Ǹjẹ́ iṣẹ́ rẹ lè sọ pé,‘Òun kò ní ọwọ́?’

10. Ègbé ni fún ẹni tí ó sọ fún baba rẹ̀ pé‘Kí ni o bí?’tàbí sí ìyá rẹ̀,‘Kí ni ìwọ ti bí?’

11. “Ohun tí Olúwa wí nìyìíẸni Mímọ́ Ísírẹ́lì, àti Ẹlẹ́dàá rẹ̀:Nípa ohun tí ó ń bọ̀,ǹjẹ́ o ń bi mí léèrè nípa àwọn ọmọ mi,tàbí kí o pàṣẹ fún mi nípa iṣẹ́ ọwọ́ mi bí?

12. Èmi ni ẹni tí ó dá ilẹ̀ ayétí ó sì da ọmọnìyàn sóríi rẹ̀.Ọwọ́ mi ni ó ti ta àwọn ọ̀runmo sì kó àwọn agbájọ ìràwọ̀ rẹ̀ síta

13. Èmi yóò gbé Kírúsì ṣókè nínú òdodo mi:Èmi yóò mú kí gbogbo ọ̀nà rẹ̀ kí ó tọ́.Òun yóò tún ìlú mi kọ́yóò sì tú àwọn àtìpó mi sílẹ̀,ṣùgbọ́n kì í ṣe fún owó tàbí ẹ̀bùn kan,ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí.”

14. Ohun tí Olúwa wí nìyìí:“Àwọn èròjà ilẹ̀ Éjíbítì àti àwọn ọjà ilẹ̀ Kúṣì,àti àwọn Ṣábíáṣì—wọn yóò wá sọ́dọ̀ rẹwọn yóò sì jẹ́ tìrẹ;wọn yóò máa wọ́ tẹ̀lé ọ lẹ́yìn,wọn yóò máa wá lọ́wọ̀ọ̀wọ́.Wọn yóò máa foríbalẹ̀ níwájú rẹ̀,wọn yóò sì máa bẹ̀bẹ̀ níwájú rẹ pé,‘Nítòótọ́ Ọlọ́run wà pẹ̀lú rẹ kò sì sí ẹlòmìíràn;kò sí ọlọ́run mìíràn.’ ”

15. Nítòótọ́ ìwọ jẹ́ Ọlọ́run tí ó fi ara rẹ̀ pamọ́,Ìwọ Ọlọ́run àti Olùgbàlà Ísírẹ́lì

16. Gbogbo àwọn tí ó ń gbẹ́ ère ni ojú yóò tìwọn yóò sì kan àbùkù;gbogbo wọn ni yóò bọ́ sínú àbùkù papọ̀.

Ka pipe ipin Àìsáyà 45