Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àìsáyà 45:21-25 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

21. Jẹ́ kí a mọ ohun tí yóò ṣẹlẹ̀, fihàn wájẹ́ kí wọn jọ dámọ̀ràn papọ̀.Ta ló ti sọ èyí lọ́jọ́ tí o ti pẹ́,ta ló ti wí èyí láti àtètèkọ́ṣe?Kì í ha á ṣe Èmi, Olúwa?Àti pé kò sí Ọlọ́run mìíràn lẹ́yìn mi,Ọlọ́run olódodo àti olùgbàlà;kò sí ẹlòmìíràn àfi èmi.

22. “Yípadà sí mi kí a sì gbà ọ́ là,ẹ̀yin ìpẹ̀kun ilẹ̀-ayé;nítorí Èmi ni Ọlọ́run kò sì sí ẹlòmìíràn.

23. Nípa èmi tìkálára mi ni mo ti búra,ẹnu mi ni ó ti sọ ọ́ pẹ̀lúu gbogbo ipá miọ̀rọ̀ náà tí a kì yóò lè parẹ́:Níwájú mi ni gbogbo orúnkún yóò wólẹ̀;nípa mi ni gbogbo ahọ́n yóò búra.

24. Wọn yóò sọ ní ti èmi, ‘Nínú Olúwa nìkan niòdodo àti agbára wà.’ ”Gbogbo àwọn tí ó ti bínú sí;yóò wá sọ́dọ̀ rẹ̀ a ó sì dójú tì wọn.

25. Ṣùgbọ́n nínú Olúwa gbogbo àwọn ìran Ísírẹ́lìni a ó rí ní òdodo, a o sì gbé wọn ga.

Ka pipe ipin Àìsáyà 45