Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àìsáyà 44:1-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. “Ṣùgbọ́n tẹ́tísílẹ̀ nísinsìn yìí, Ìwọ Jákọ́bù,Ìránṣẹ́ miÍsírẹ́lì, ẹni tí mo ti yàn.

2. Ohun tí Olúwa wí nìyìíẹni tí ó dá ọ, ẹni tí ó ti mọ̀ ọ́láti inú ìyá rẹ wá,àti ẹni tí yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ pẹ̀lú:Má ṣe bẹ̀rù, Ìwọ Jákọ́bù, ìránṣẹ́ mi,Jéṣúrúnì ẹni tí mo ti yàn.

3. Nítorí èmi yóò da omi sí ilẹ̀ tí ń pòǹgbẹàti àwọn odò ni ilẹ̀ gbígbẹ;Èmi yóò tú Ẹ̀mí mi sí ara àwọn ọmọ rẹ,àti ìbùkún mi sóri àwọn àrọ́mọdọ́mọ rẹ.

4. Wọn yóò dàgbà ṣókè gẹ́gẹ́ bí i koríko nínúpápá oko tútù,àti gẹ́gẹ́ bí igi póǹpóla léti odò tí ń sàn.

5. Ọ̀kan yóò wí pé, ‘Èmi jẹ́ ti Olúwa’;òmìíràn yóò pe ara rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí orúkọ Jákọ́bù;bẹ́ẹ̀ ni òmìíràn yóò kọ ọ́ sí ọwọ́ rẹ̀, Ti Olúwa,yóò sì máa jẹ́ orúkọ náà Ísírẹ́lì.

6. “Ohun tí Olúwa wí nìyìíọba Ísírẹ́lì àti Olùdáǹdè, àní Olúwa àwọn ọmọ-ogun:Èmi ni ẹni àkọ́kọ́ àti ẹni ìgbẹ̀yìn,lẹ́yin mi kò sí Ọlọ́run kan.

7. Ta ni ó dàbí ì mi? Jẹ́ kí o kéde rẹ̀.Jẹ́ kí ó wí kí ó sì gbé síwájú miKí ni ó ti ṣẹlẹ̀ láti ìgbà tí mo fi ìdíàwọn ènìyàn ìṣẹ̀ǹbáyé kalẹ̀,àti kí ni ohun tí ń sì ń bọ̀bẹ́ẹ̀ ni, jẹ́ kí ó sọ aṣọtẹ́lẹ̀ ohun tí ń bọ̀ wá.

8. Má ṣe wárìrì, má ṣe bẹ̀rù.Ǹjẹ́ èmi kò ti kéde èyí tí mo sì ti sọàṣọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ típẹ́típẹ́?Ẹ̀yin ni ẹlẹ́rìí mi. Ǹjẹ́ Ọlọ́run kanha ń bẹ lẹ́yìn mi?Bẹ́ẹ̀ kọ́, kò sí àpáta mìíràn; Èmi kò mọ ọ̀kankan.”

9. Gbogbo àwọn tí ń gbẹ́ ère jásí asán,àti àwọn ohun tí wọn ń kó pamọ́kò jámọ́ nǹkankan.Àwọn tí yóò sọ̀rọ̀ fún wọn fọ́ lójú;wọ́n jẹ́ aláìmọ́kan sí ìtìjú ara wọn.

10. Ta ni ó mọ òrìṣà kan tí ó sì ya ère,tí kò lè mú èrè kankan wá fún un?

Ka pipe ipin Àìsáyà 44