Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àìsáyà 43:14-22 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

14. Èyí ni ohun tí Olúwa wíolùràpadà rẹ, Ẹni Mímọ́ ti Ísírẹ́lì;“Nítorí rẹ Èmi yóò ránṣẹ́ sí Bábílónìláti mú wọn sọ̀kalẹ̀ wá gẹ́gẹ́ bí ìsáǹsá,gbogbo ará Bábílónìnínú ọkọ̀ ojú omi nínú èyí tí wọ́n fi ń ṣe ìgbéraga.

15. Èmi ni Olúwa, Ẹni Mímọ́ rẹ,Ẹlẹ́dàá Ísírẹ́lì, ọba rẹ.”

16. Èyí ni ohun tí Olúwa wíẸni náà tí ó la ọ̀nà nínú òkun,ipa-ọ̀nà láàrin alagbalúgbú omi,

17. ẹni tí ó wọ́ àwọn kẹ̀kẹ́ àti ẹṣin jáde,àwọn jagunjagun àti ohun ìjà papọ̀,wọ́n sì ṣùn ṣíbẹ̀, láìní lè dìde mọ́,wọ́n kú pirá bí òwú fìtílà:

18. “Gbàgbé àwọn ohun àtẹ̀yìnwá;má ṣe gbé nínú ohun àtijọ́.

19. Wò ó, Èmi ń ṣe ohun tuntun!Nísinsìn yìí ó ti yọ ṣókè; àbí o kò rí i bí?Èmi ń ṣe ọ̀nà kan nínú aṣálẹ̀àti odò nínú ilẹ̀ ṣíṣá.

20. Àwọn ẹhànnà ẹranko bọ̀wọ̀ fún mi,àwọn ajáko àti àwọn òwìwí,nítorí pé mo pèṣè omi nínú aṣálẹ̀àti odò nínú ilẹ̀ ṣíṣá,láti fi ohun-mímu fún àwọn ènìyàn mi, àyànfẹ́ mi,

21. àwọn ènìyàn tí mo dá fún ara mikí wọn kí ó lè kéde ìyìn mi.

22. “Ṣíbẹ̀ ṣíbẹ̀ ìwọ kò tí ì ké pè mí,Ìwọ Jákọ́bù,àárẹ̀ kò tí ì mú ọ nítoríì miÌwọ Ísírẹ́lì.

Ka pipe ipin Àìsáyà 43