Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àìsáyà 43:12-19 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

12. Èmi ti fihàn, mo gbàlà mo sì ti kédeÈmi, kì í sì í ṣe àwọn àjèjì òrìṣà láàrin yín.Ẹ̀yin ni ẹlẹ́rìí mi,” ni Olúwa wí,“Pé Èmi ni Ọlọ́run.

13. Bẹ́ẹ̀ ni, àti láti ayérayé Èmi ni ẹni náà.Kò sí ẹnikẹ́ni tí ó lè gbà kúrò lọ́wọ́ mi.Nígbà tí mo bá ṣe nǹkan, ta ni ó lè yí i padà?”

14. Èyí ni ohun tí Olúwa wíolùràpadà rẹ, Ẹni Mímọ́ ti Ísírẹ́lì;“Nítorí rẹ Èmi yóò ránṣẹ́ sí Bábílónìláti mú wọn sọ̀kalẹ̀ wá gẹ́gẹ́ bí ìsáǹsá,gbogbo ará Bábílónìnínú ọkọ̀ ojú omi nínú èyí tí wọ́n fi ń ṣe ìgbéraga.

15. Èmi ni Olúwa, Ẹni Mímọ́ rẹ,Ẹlẹ́dàá Ísírẹ́lì, ọba rẹ.”

16. Èyí ni ohun tí Olúwa wíẸni náà tí ó la ọ̀nà nínú òkun,ipa-ọ̀nà láàrin alagbalúgbú omi,

17. ẹni tí ó wọ́ àwọn kẹ̀kẹ́ àti ẹṣin jáde,àwọn jagunjagun àti ohun ìjà papọ̀,wọ́n sì ṣùn ṣíbẹ̀, láìní lè dìde mọ́,wọ́n kú pirá bí òwú fìtílà:

18. “Gbàgbé àwọn ohun àtẹ̀yìnwá;má ṣe gbé nínú ohun àtijọ́.

19. Wò ó, Èmi ń ṣe ohun tuntun!Nísinsìn yìí ó ti yọ ṣókè; àbí o kò rí i bí?Èmi ń ṣe ọ̀nà kan nínú aṣálẹ̀àti odò nínú ilẹ̀ ṣíṣá.

Ka pipe ipin Àìsáyà 43