Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àìsáyà 43:1-7 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ṣùgbọ́n ní ìsinsìn yìí, ohun tí Olúwa wí nìyìíẹni tí ó dá ọ, Ìwọ Jákọ́bùẹni tí ó mọ ọ́, Ìwọ Ísírẹ́lì:“Má bẹ̀rù, nítorí Èmi ti dá ọ nídè;Èmi ti pè ọ́ ní orúkọtèmi ni ìwọ ṣe.

2. Nígbà tí ìwọ bá ń la omi kọjá,Èmi yóò wà pẹ̀lúu rẹ;àti nígbà tí ìwọ bá ń la odò kọjáwọn kì yóò bò ọ́ mọ́lẹ̀.Nígbà tí ìwọ bá la iná kọjá,kò ní jó ọ;ahọ́n iná kò ní jó ọ lára.

3. Nítorí Èmi ni Olúwa Ọlọ́run rẹ,Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì Olùgbàlà rẹ;Èmi fi Éjíbítì ṣe ìràpadà rẹ,Kúṣì àti Ṣébà dípò rẹ.

4. Nítorí pé o ṣe iyebíye àti ọ̀wọ́n níwájú mi,àti nítorí pé mo fẹ́ràn rẹ,Èmi yóò fi ènìyàn rọ́pò fún ọ,àti ènìyàn dípò ẹ̀míì rẹ.

5. Má bẹ̀rù nítorí èmi wà pẹ̀lúù rẹ;Èmi yóò mú àwọn ọmọ rẹ láti ìlà oòrùn wáèmi ó sì kó ọ jọ láti ìwọ̀ oòrùn.

6. Èmi yóò sọ fún àríwá pé, ‘Fi wọ́n sílẹ̀!’àti fún gúṣù, ‘Má ṣe dá wọn dúró.’Mú àwọn ọmọkùnrin mi láti ọ̀nà jínjìn wáàti àwọn ọ̀dọ́mọbìnrin mi láti ìpẹ̀kun ilẹ̀ ayé—

7. ẹnikẹ́ni tí a ń pe orúkọ mi mọ́,tí mo dá fún ògo mi,tí mo mọ̀ àti tí mo ṣe.”

Ka pipe ipin Àìsáyà 43