Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àìsáyà 42:16-25 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

16. Èmi yóò tọ àwọn afọ́jú ní ọ̀nà tí wọn kò tí ì mọ̀,ní ipa-ọ̀nà tí ó ṣàjèjì sí wọn ni èmi yóò tọ́ wọn lọ;Èmi yóò sọ òkùnkùn di ìmọ́lẹ̀ níwájúu wọnàti ibi pálapàla ni èmi ó sọ di kíkúnná.Àwọn nǹkan tí máa ṣe nìyìí;Èmi kì yóò kọ̀ wọ́n sílẹ̀.

17. Ṣùgbọ́n àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀lé òrìṣà,tí wọ́n wí fún ère pé, ‘Ẹ̀yin ni Ọlọ́run wa,’ni a ó dá padà pẹ̀lú ìtìjú.

18. “Gbọ́, ìwọ adití,wòó, ìwọ afọ́jú, o sì rí!

19. Ta ló fọ́jú bí kò ṣe ìránṣẹ́ mi,àti odi gẹ́gẹ́ bí oníṣẹ́ tí mo rán?Ta ni ó fọ́jú gẹ́gẹ́ bí ẹni tí a fi jìnmí,ó fọ́jú gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ Olúwa?

20. Ẹ̀yin ti rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ nǹkan, ṣùgbọ́n ẹ kò ṣe àkíyèsí;etí yín yà sílẹ̀, ṣùgbọ́n ẹ kò gbọ́ nǹkankan.”

21. Ó dùn mọ́ Olúwanítorí òdodo rẹ̀láti mú òfin rẹ lágbára àti ògo.

22. Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn kan níyìí tí a jà lóguntí a sì kó lẹ́rú,gbogbo wọn ni ó wà nínú ọ̀gbun,tàbí tí a fi pamọ́ sínú ẹ̀wọ̀n.Wọ́n ti di ìkógun,láìsí ẹnìkan tí yóò gbà wọ́n sílẹ̀;wọ́n ti di ìkógun,láìsí ẹni tí yóò sọ pé, “Dá wọn padà.”

23. Ta ni nínú un yín tí yóò tẹ́tí sí èyítàbí kí ó ṣe àkíyèsí gidi ní àsìkò tí ó ń bọ̀?

24. Ta ni ó fi Jákọ́bù lélẹ̀ fún ìkógun,àti Ísírẹ́lì sílẹ̀ fún onísùnmọ̀mí?Kì í há ṣe Olúwa ni,ẹni tí àwa ti ṣẹ̀ sí?Nítorí pé wọn kò ní tẹ̀lé ọ̀nà rẹ̀;wọn kò mú òfin rẹ̀ ṣẹ.

25. Nítorí náà ni ó ṣe rọ̀jò ìbínú un rẹ̀ lé wọn lórí,rògbòdìyàn ogun.Èyí tí ó fi ahọ́n iná yí wọn po, síbẹ̀èdè kò yé wọn;ó jó wọn run, síbẹ̀ wọn kò fi sọ́kàn wọn rárá.

Ka pipe ipin Àìsáyà 42