Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àìsáyà 40:10-20 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

10. Wò ó, Olúwa àwọn ọmọ-ogun náà ń bọ̀ wá pẹ̀lú agbára,apá rẹ̀ sì ń jọba fún un.Wò ó, ère rẹ̀ sì wà pẹ̀lúu rẹ̀,àti ìdápadà rẹ̀ tí ń bá a bọ̀ wá.

11. Ó ń tọ́ àwọn agbo rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí olùṣọ́-àgùntàn:Ó kó àwọn ọ̀dọ́-àgùntàn ní apá rẹ̀.Ó sì gbé wọn súnmọ́ oókan-àyàa rẹ̀;ó sì fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ da rí àwọn tí ó ní ọ̀dọ́.

12. Ta ni ó ti wọn omi nínú kòtò ọwọ́ rẹ̀,tàbí pẹ̀lú ìbú ọwọ́ rẹ̀tí ó wọn àwọn ọ̀run?Ta ni ó ti kó erùpẹ̀ ilẹ̀-ayé jọ nínú apẹ̀rẹ̀,tàbí kí ó wọn àwọn òkè ńlá lórí ìwọ̀nàti òkè kéékèèkéé nínú òṣùwọ̀n?

13. Ta ni ó ti mọ ọkàn Olúwa,tàbí tí ó ti tọ́ ọ sọ́nà gẹ́gẹ́ bí olùdámọ̀ràn rẹ̀?

14. Ta ni Olúwa ké sí kí ó là á lọ́yẹàti ta ni ó kọ́ òun ní ọ̀nà tí ó tọ́?Ta ni ẹni náà tí ó kọ́ ọ ní ọgbọ́ntàbí tí ó fi ipa ọ̀nà òye hàn án?

15. Nítòótọ́ àwọn orílẹ̀ èdè dàbí i ẹ̀kán-ominínú garawa;a kà wọ́n sí gẹ́gẹ́ bí eruku lórí ìwọ̀n;ó wọn àwọn erékùṣù àfi bí eruku múnúmúnú ni wọ́n.

16. Lẹ́bánónì kò tó fún pẹpẹ iná,tàbí kí àwọn ẹranko rẹ̀ kí ó tó fún ẹbọ sísun.

17. Níwájúù rẹ ni gbogbo orílẹ̀ èdè dàbí ohun tí kò sí;gbogbo wọn ló kà sí ohun tí kò wúlòtí kò tó ohun tí kò sí.

18. Ta ni nígbà náà tí ìwọ yóò fi Ọlọ́run wé?Ère wo ni ìwọ yóò fi ṣe àkàwé rẹ̀?

19. Ní ti ère, oníṣọ̀nà ni ó dà á,ti alágbẹ̀dẹ wúrà sì fi wúrà bò ótí a sì ṣe ẹ̀wọ̀n ọ̀nà sílífà fún un.

20. Ọkùnrin kan tí ó talákà ju kí ó lè múirú ọrẹ bẹ́ẹ̀ wá,wá igi tí kò le è rà.Ó wá oníṣọ̀nà tí ó dáńtọ́láti ṣe àgbékalẹ̀ ère tí kì yóò le è ṣubú.

Ka pipe ipin Àìsáyà 40