Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àìsáyà 37:32-38 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

32. Nítorí láti Jérúsálẹ́mù ni àwọn àṣẹ́kù yóò ti wá,àti láti òkè Ṣíhónì ni ikọ̀ àwọn tí ó sálà.Ìtara Olúwa àwọn ọmọ-ogun ni yóò mú èyí ṣẹ.

33. “Nítorí náà, èyí ni ohun tí Olúwa wí nípa ọba Ásíríà:“Òun kì yóò wọ ìlú yìí wátàbí ta ẹyọ ọfà kan níhìn-ínÒun kì yóò wá síwájúu rẹ pẹ̀lú asàtàbí kí ó kó dágunró sílẹ̀ fún un.

34. Nípa ọ̀nà tí ó gbàwá náà ni yóò padà lọ;òun kì yóò wọ inú ìlú yìí,”ni Olúwa wí.

35. “Èmi yóò dáàbò bo ìlú yìí èmi ó sì gbàá là,nítorí mi àti nítoríì Dáfídì ìránṣẹ́ mi!”

36. Lẹ́yìn náà ni ańgẹ́lì Olúwa jáde lọ ó sì pa ọ̀kẹ́ mẹ́sàn án ó lé ẹgbẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n ènìyàn ní i ibùdó àwọn Ásíríà. Nígbà tí àwọn ènìyàn yìí jí ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì gbogbo wọn ti dòkú!

37. Nítorí náà Ṣenakérúbù ọba Ásíríà fọ́ bùdó ó sì pẹṣẹ̀dà. Òun sì padà sí Nínéfè, ó sì dúró síbẹ̀.

38. Ní ọjọ́ kan, bí ó ti ń jọ́sìn nínú tẹ́ḿpìlì Níṣírókì òrìṣà rẹ, àwọn ọmọ rẹ̀ Adiramélékì àti Ṣáréṣà gé e lulẹ̀ pẹ̀lú idà, wọ́n sì sá lọ sí ilẹ̀ Árárátì. Bẹ́ẹ̀ ni Ẹsahadoni ọmọ rẹ̀ sì gba ipo rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba.

Ka pipe ipin Àìsáyà 37