Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àìsáyà 37:26-31 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

26. “Ṣé o kò tí ì gbọ́?Tipẹ́ tipẹ́ ni mo ti fìdíi rẹ̀ mulẹ̀.Láti ìgbà pípẹ́ ni mo ti ṣètò rẹ̀;ní àkókò yìí ni mo mú wá sí ìmúṣẹ,pé o ti sọ àwọn ìlú olódi diàkójọpọ̀ àwọn òkúta

27. Àwọn ènìyàn, tí agbára ti wọ̀ lẹ́wù,ni wọ́n banújẹ́ tí a sì dójútì.Wọ́n dàbí ohun ọ̀gbìn nínú pápá,gẹ́gẹ́ bí ọ̀jẹ̀lẹ̀ èhù tuntun,gẹ́gẹ́ bí i koríko tí ó ń hù lórí òrùlé,tí ó jóná kí ó tó dàgbà ṣókè.

28. “Ṣùgbọ́n mo mọ ibi tí o wààti ìgbà tí o wá tí o sì lọàti bí inú rẹ ṣe ru sími.

29. Nítorí pé inú rẹ ru símiàti nítorí pé oríkunkun rẹ tidé etíìgbọ́ mi,Èmi yóò fi ìwọ mi sí ọ ní imú,àti ìjẹ mi sí ọ lẹ́nu,èmi yóò sì jẹ́ kí o padàláti ọ̀nà tí o gbà wá.

30. “Èyí ni yóò ṣe àmì fún ọ Ìwọ Heṣekáyà:“Ní ọdún yìí, ìwọ yóò jẹ ohun tí ó hù fúnraà rẹ̀,àti ní ọdún kejì ohun tí ó jáde láti ara ìyẹn.Ṣùgbọ́n ní ọdún kẹta, ẹ gbìn kí ẹ sì kórè,ẹ gbin ọgbà àjàrà kí ẹ sì jẹ èṣo wọn.

31. Lẹ́ẹ̀kan sí i, àṣẹ́ku láti ilé Júdàyóò ta gbòǹgbò níṣàlẹ̀ yóò sì ṣo èṣo lókè.

Ka pipe ipin Àìsáyà 37