Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àìsáyà 36:11-22 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

11. Lẹ́yìn náà ni Eliákímù, Ṣébínà àti Jóà sọ fún ọ̀gágun náà pé, “Jọ̀wọ́ máa bá àwọn ìránṣẹ́ rẹ sọ̀rọ̀ ní èdè Árámáíkì, nítorí pé àwa gbọ́ ọ. Má ṣe bá wa sọ̀rọ̀ ní èdè Hébérù ní etí àwọn ènìyàn tí ó wà lórí ògiri mọ́.”

12. Ṣùgbọ́n ọ̀gágun náà dá wọn lóhùn pé, “Ṣé ẹ rò wí pé ọ̀gá yín àti ẹ̀yin nìkan ni ọ̀gá mi rán mi sí láti sọ nǹkan wọ̀nyí fún ni, tí kì í sì ṣe sí àwọn ènìyàn wọ̀nyí tí ó jókòó lórí ògiri, àwọn tí ó jẹ́ pé wọn yóò jẹ ìgbẹ́ wọn tí wọ́n yóò sì mu ìtọ wọn gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin náà?”

13. Lẹ́yìn náà ni ọ̀gágun náà dìde tí ó sì ké sítà ní èdè Hébérù pé, “Ẹ gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ ọba ńlá, ọba Ásíríà!

14. Ohun tí ọba wí nìyìí: Ẹ má ṣe jẹ́ kí Heṣekáyà tàn yín jẹ. Òun kò le è gbà yín sílẹ̀!

15. Ẹ má ṣe jẹ́ kí Heṣekáyà rọ̀ yín láti gbẹ́kẹ̀lé Olúwa nígbà tí ó sọ pé, ‘Olúwa yóò kúkú gbà wá; a kì yóò fi ìlú lé ọba Ásíríà lọ́wọ́.’

16. “Ẹ má ṣe tẹ́tí sí Heṣekáyà. Ohun tí ọba Áṣíríà wí nìyìí: Ẹ ṣètò àlàáfíà pẹ̀lúù mi kí ẹ sì jáde tọ̀ mí wá. Lẹ́yìn náà ẹnìkọ̀ọ̀kan yín yóò sì jẹ nínú àjàrà àti igi ọ̀pọ̀tọ́ rẹ̀ bẹ́ẹ̀ ni yóò sì mumi nínú kàǹga rẹ̀,

17. títí tí èmi yóò fi mú un yín lọ sí ilẹ̀ kan tí ó dàbí i ti yín, ilẹ̀ tí ó ní irúgbìn oníhóró àti wáìnì tuntun, ilẹ̀ tí ó ní àkàrà àti ọgbà àjàrà.

18. “Ẹ má ṣe jẹ́ kí Heṣekáyà sì yín lọ́nà nígbà tí ó sọ wí pé, ‘Olúwa yóò gbà wá.’ Ǹjẹ́ ọlọ́run orílẹ̀ èdè kan ha ti gbà á kúrò lọ́wọ́ ọba Áṣíríà bí?

19. Níbo ni àwọn òrìṣà Hámátì àti Ápádì ha wà? Níbo ni àwọn òrìṣà Ṣépáfírámù ha wà? Ǹjẹ́ wọn ti já Ṣamáríà gbà kúrò lọ́wọ́ mi bí?

20. Èwo nínú àwọn òrìṣà orílẹ̀ èdè wọ̀nyí ló ha ti dáàbò bo ilẹ̀ẹ rẹ̀ kúrò lọ́wọ́ mi? Báwo ni Olúwa ṣe wá le gba Jérúsálẹ́mù kúrò lọ́wọ́ mi?”

21. Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn náà dákẹ́ rọ́rọ́ wọn kò sì mú èsì kankan wá, nítorí ọba ti pàṣẹ fún wọn pé, “Ẹ má ṣe dá a lóhùn.”

22. Lẹ́yìn náà ni Eliákímù ọmọ Híkílíà alákóṣo ààfin, Ṣébínà akọ̀wé àti Jóà ọmọ Áṣáfù akọ̀wé àkọsílẹ̀ lọ sí ọ̀dọ̀ Heṣekáyà pẹ̀lú aṣọ wọn ní fífàya, wọ́n sì sọ ohun tí ọ̀gágun ti wí.

Ka pipe ipin Àìsáyà 36