Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àìsáyà 34:1-7 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Súnmọ́ tòsí,ẹ̀yin orílẹ̀-èdè láti gbọ́,tẹ́tísílẹ̀ ẹyín ènìyànjẹ́ kí ayé gbọ́,àti ẹ̀kún rẹ̀,ayé àti ohun gbogbo tí ó ti inú un rẹ̀ jáde.

2. Nítorí ibínú Olúwa ń bẹlára gbogbo orílẹ̀-èdè,àti irunú un rẹ̀ lórí gbogbo ogun wọn:o ti fi wọ́n fún pipa,

3. Àwọn ti a pa nínú un wọnni a ó sì jù ṣóde,òórùn wọn yóò ti inú òkúu wọn jáde,àwọn òkè-ńlá yóò sì yọ̀ nínú ẹ̀jẹ̀ wọn

4. Gbogbo àwọn ogun ọ̀run ni yóò di yíyọ́,a ó sì ká àwọn ọ̀run jọ bí i takàdá,gbogbo ogun wọn yóò si ṣubú lulẹ̀,bí ewé ti n bọ́ kúrò lára àjàrà,àti bí i bíbọ́ èṣo lára igi ọ̀pọ̀tọ́.

5. Nítorí ti a rẹ idà mi ní ọ̀run,kíyèsì í, yóò ṣọ̀kalẹ̀ wá sórí Édómù,sórí àwọn ènìyàn tí mo ti parun fún ìdájọ.

6. Idà Olúwa kún fún ẹ̀jẹ̀a mú un ṣanra fún ọ̀rá,àti fún ẹ̀jẹ̀ ọ̀dọ́-agùtàn àti ewurẹ,fún ọ̀rá iwe àgbò—nítorí Olúwa ni ìrúbọ kan ní Bósírà,àti ìpakúpa ńlá kan ní ilẹ̀ Édómù.

7. Àti àwọn àgbáǹréré yóòba wọn ṣọ̀kalẹ̀ wá,àti àwọn ẹgbọ̀rọ̀ màlúùpẹ̀lú àwọn akọ màlúù,ilé wọn ni a ó fi ẹ̀jẹ̀ rin,a ó si fi ọ̀rá sọ ekuru wọn di Ọlọ́ràá.

Ka pipe ipin Àìsáyà 34