Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àìsáyà 32:14-19 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

14. Ilé olódi ni a ó kọ̀ sílẹ̀,ìlù aláriwo ni a ó kọ̀tì;ilé olódi àti ilé ìṣọ́ ni yóò di ìdànù títí láéláé,ìdùnnú àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ àti pápáoko fún àwọn ẹran ọ̀sìn,

15. títí a ó fi tú Ẹ̀mí sí wa lórí láti òkè wá,àti ti aṣálẹ̀ tí yóò dí pápá oko ọlọ́ràáàti tí pápá ọlọ́ràá yóò dàbí ẹgàn.

16. Ẹ̀tọ́ yóò máa gbé ní inú aṣálẹ̀àti òdodo yóò sì máa gbé ní pápá oko ọlọ́ràá.

17. Èṣo òdodo náà yóò sì jẹ́ àlàáfíà;àbájáde òdodo yóò sì jẹ́ ìdákẹ́jẹ́ àti ìgbẹ́kẹ̀lé títí láé.

18. Àwọn ènìyàn mi yóò máa gbé ní àlàáfíà ní ibùgbé àlàáfíà,ní àwọn ilé ààbò,ní àwọn ibi ìsinmi tí kò ti sí ìdíwọ́.

19. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé yìnyín ti tẹ́jú igbó pẹrẹṣẹàti tí ojú ìlú ti tẹ́ pẹrẹṣẹ pátapáta,

Ka pipe ipin Àìsáyà 32