Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àìsáyà 30:6-15 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

6. Ọ̀rọ̀-ìmọ̀ sí àwọn ẹranko tí ó wà ní Gúúsù:Láàrin ilẹ̀ ìnira àti ìpọ́njú,ti kìnnìún àti abo kìnnìúnti pamọ́lẹ̀ àti ejò olóró,àwọn ikọ̀ náà kó ẹrù àti ọrọ̀wọn lẹ́yìn àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́,àwọn ohun ìní wọn ní orí iké àwọn ràkunmí,sí orílẹ̀ èdè aláìlérè,

7. sí Éjíbítì tí ìrànlọ́wọ́ rẹ̀kò wúlò rárá.Nítorí náà mo pè é níRáhábù Aláìlẹ́sẹ̀ nǹkankan.

8. Lọ nísinsìn yìí, kí o sì kọ ọ́ sí ara pátakó fún wọn,tẹ̀ ẹ́ sí ara ìwé kíká,pé fún àwọn ọjọ́ tí ó ń bọ̀kí ó sì lè jẹ́ ẹ̀rí ayérayé.

9. Àwọn wọ̀nyí jẹ́ ọlọ̀tẹ̀ ènìyànàti ẹlẹ́tanu ọmọ,àwọn ọmọ tí wọn kò ṣetán láti tẹ́tí síìtọ́ni Olúwa.

10. Wọ́n sọ fún àwọn aríran pé,“Ẹ má ṣe rí ìran mọ́!”àti fún àwọn wòlíì,“Ẹ má ṣe fi ìran ohun tí ó tọ́ hàn wá mọ́!Ẹ sọ ohun tí ó tura fún wa,ẹ sàsọtẹ́lẹ̀ ẹ̀tàn.

11. Ẹ fi ọ̀nà yìí sílẹ̀,ẹ kúrò ní ọ̀nà yìíẹ dẹ́kun à ń dojú ìjà kọwápẹ̀lú Ẹni-Mímọ́ Ísírẹ́lì!”

12. Nítorí náà, èyí ni ohun tí Ẹni-Mímọ́ Ísírẹ́lì wí:“Nítorí pé ẹ ti kọ ọ̀rọ̀ yìí sílẹ̀,ẹ gbáralé ìnilárakí ẹ sì gbọ́kànlé ẹ̀tàn,

13. ẹ̀ṣẹ̀ yìí yóò rí fún ọgẹ́gẹ́ bí ògiri gíga, tí ó sán tí ó sì fìtí ó sì wó lójijì, àti ńi ìṣẹ́jú àáyá.

14. Yóò sì fọ́ ọ sí wẹ́wẹ́ bí àpáàdìtí a fọ́ yánkanyànkanàti pé a kò ní rí ẹ̀rún kan nínú àfọ́kù rẹ̀,fún mímú èédú kúrò nínú ààròtàbí gbígbọ́n omi jáde kúrò nínú àmù.”

15. Èyí ni ohun tí Olúwa alágbára, Ẹni-Mímọ́ ti Ísírẹ́lì wí:“Nínú ìrònúpìwàdà àti ìsinmi ni ìgbàlà rẹ wà,ní ìdákẹ́jẹ́ ẹ́ àti ìgbẹ́kẹ̀lé ni agbára rẹ wà,ṣùgbọ́n ìwọ kì yóò ní ọ̀kankan nínú wọn.

Ka pipe ipin Àìsáyà 30