Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àìsáyà 30:31-33 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

31. Ohùn Olúwa yóò fọ́ Áṣíríà túútúú,pẹ̀lú ọ̀pá aládé rẹ̀ ni yóò lù wọ́n bolẹ̀.

32. Ẹgba kọ̀ọ̀kan tí Olúwa bá gbé lé wọnpẹ̀lú ọ̀pá ìjẹníyà rẹ̀yóò jẹ́ ti ìlù tamborínì àti ti hápù,gẹ́gẹ́ bí ó ti ń bá wọn jà lójú ogunpẹ̀lú ẹ̀sẹ́ láti apá rẹ̀.

33. A ti tọ́jú Tófẹ́tì sílẹ̀ tipẹ́tipẹ́,a ti tọ́jú rẹ̀ sílẹ̀ fún ọba.Ojú ààrò rẹ̀ ni a ti gbẹ́ jìn tí ó sì fẹ̀,pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ iná àti igi ìdáná;èémí Olúwa,gẹ́gẹ́ bí ìsàn ṣúfúrù tí ń jó ṣe mú un gbiná.

Ka pipe ipin Àìsáyà 30