Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àìsáyà 30:1-12 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. “Ègbé ni fún orílẹ̀-èdè alágídí náà,”ni Olúwa wí,“Fún àwọn tí ó gbé ètò jáde tí kì í ṣe tèmi,tí wọ́n ń gbìmọ̀ pọ̀, ṣùgbọ́n kì í ṣe nípa Ẹ̀mí mi,tí wọ́n ń dá ẹ̀ṣẹ̀ lórí ẹ̀ṣẹ̀;

2. tí wọ́n lọ sí Éjíbítìláì ṣe fún mi,tí ó ń wá ìrànlọ́wọ́ lọ́dọ̀ Fáráò fún ààbò,sí òjìji, Éjíbítì fún ibi ìsádi.

3. Ṣùgbọ́n ààbò Fáráò yóò já sí ìtìjú fún un yín,òjìji Éjíbítì yóò mú àbùkù báa yín.

4. Bí wọ́n tilẹ̀ ní àwọn òṣìṣẹ́ ní Sóánìtí àwọn ikọ̀ wọn sì ti dé sí Hánísì,

5. gbogbo wọn ni a ó dójútì,nítorí àwọn ènìyàn kan tí kò wúlò fún wọn,tí kò mú ìrànlọ́wọ́ tàbí àǹfààní wá,bí kò ṣe àbùkù àti ìdójúti ni.”

6. Ọ̀rọ̀-ìmọ̀ sí àwọn ẹranko tí ó wà ní Gúúsù:Láàrin ilẹ̀ ìnira àti ìpọ́njú,ti kìnnìún àti abo kìnnìúnti pamọ́lẹ̀ àti ejò olóró,àwọn ikọ̀ náà kó ẹrù àti ọrọ̀wọn lẹ́yìn àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́,àwọn ohun ìní wọn ní orí iké àwọn ràkunmí,sí orílẹ̀ èdè aláìlérè,

7. sí Éjíbítì tí ìrànlọ́wọ́ rẹ̀kò wúlò rárá.Nítorí náà mo pè é níRáhábù Aláìlẹ́sẹ̀ nǹkankan.

8. Lọ nísinsìn yìí, kí o sì kọ ọ́ sí ara pátakó fún wọn,tẹ̀ ẹ́ sí ara ìwé kíká,pé fún àwọn ọjọ́ tí ó ń bọ̀kí ó sì lè jẹ́ ẹ̀rí ayérayé.

9. Àwọn wọ̀nyí jẹ́ ọlọ̀tẹ̀ ènìyànàti ẹlẹ́tanu ọmọ,àwọn ọmọ tí wọn kò ṣetán láti tẹ́tí síìtọ́ni Olúwa.

10. Wọ́n sọ fún àwọn aríran pé,“Ẹ má ṣe rí ìran mọ́!”àti fún àwọn wòlíì,“Ẹ má ṣe fi ìran ohun tí ó tọ́ hàn wá mọ́!Ẹ sọ ohun tí ó tura fún wa,ẹ sàsọtẹ́lẹ̀ ẹ̀tàn.

11. Ẹ fi ọ̀nà yìí sílẹ̀,ẹ kúrò ní ọ̀nà yìíẹ dẹ́kun à ń dojú ìjà kọwápẹ̀lú Ẹni-Mímọ́ Ísírẹ́lì!”

12. Nítorí náà, èyí ni ohun tí Ẹni-Mímọ́ Ísírẹ́lì wí:“Nítorí pé ẹ ti kọ ọ̀rọ̀ yìí sílẹ̀,ẹ gbáralé ìnilárakí ẹ sì gbọ́kànlé ẹ̀tàn,

Ka pipe ipin Àìsáyà 30