Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àìsáyà 28:21-29 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

21. Olúwa yóò dìde sókè gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣení òkè Péráṣímùyóò ru ara rẹ̀ ṣókè gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣení àfonífojì Gíbíónì—láti ṣe iṣẹ́ rẹ̀, abàmì iṣẹ́ ẹ rẹ̀,yóò ṣe iṣẹ́ rẹ̀, àní àjèjì iṣẹ́ rẹ̀.

22. Ní ìsinsìn yìí ẹ dákẹ́ ẹlẹ́yà ṣíṣe,bí bẹ́ẹ̀ kọ́ ìdè e yín yóò le sí i; Olúwa, àní Olúwa àwọn-ogun ti sọ fún minípa àṣẹ ìparun ti ó ti pa lórí gbogbo ilẹ̀ náà.

23. Tẹ́tí kí o sì gbọ́ ohùn mi,fi ara balẹ̀ kí o sì gbọ́ ohun tí mo sọ.

24. Nígbà tí àgbẹ̀ kan bá tu ilẹ̀ láti gbìnyóò ha máa tulẹ̀ títí títí ni?Ǹjẹ́ yóò ha máa tu ilẹ̀ kíó sì máa jọ̀ ọ́ títí lọ bí?

25. Lẹ́yìn ìgbà tí ó bá ti tẹ́ ilẹ̀ pẹrẹṣẹòun kì yóò ha gbìn káráwè kíó sì fọ́n irúgbìn kúmínì ká bí?Òun kì yóò ha gbin jéró sí àyè e tirẹ̀ọkà báálì sì àyè e tirẹ̀,àti Ṣípẹ́lítì ní oko tirẹ̀?

26. Ọlọ́run rẹ̀ tọ́ ọ sọ́nàó sì kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ ní ọ̀nà tótọ́.

27. A kì í fi òòlù pa káráwétàbí kẹ̀kẹ́-ẹrù là á fi yí kúmínì mọ́lẹ̀;ọ̀pá ni a fi ń lu káráwé,àti kúmínì pẹ̀lú igi.

28. A gbọdọ̀ lọ hóró kí a tó ṣe àkàrà;bẹ́ẹ̀ ni ẹnìkan kì í máa pa á lọ títí láé.Bí ó tilẹ̀ yí ẹṣẹ̀ kẹ̀kẹ́ ìpakà a rẹ̀ lóríi rẹ̀,àwọn ẹṣin rẹ̀ kò le lọ̀ ọ́.

29. Gbogbo èyí pẹ̀lú ti ọ̀dọ̀ Olúwa àwọn ọmọ-ogun wá,oníyanu ní ìmọ̀ràn àti ológo ní ọgbọ́n.

Ka pipe ipin Àìsáyà 28