Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àìsáyà 28:1-8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ègbé ni fún òdòdó-ẹ̀yẹ náà, tí í ṣeìgbéraga àwọn ọ̀mùtí Éfáímù,àti sí òdòdó náà tí ń rọ, tí í ṣeògo ẹwàa rẹ̀,tí ó tò sí orí àfonífojì ẹlẹ́tù lójúàti sí ìlú náà ìgbéraga àwọn tía rẹ̀ sílẹ̀ láti ọ̀dọ̀ wáìnì!

2. Kíyèsíì, Olúwa ní ẹnìkan tí ó le tí ó sì lágbára,gẹ́gẹ́ bí ẹ̀wọ́ yìnyín àti bí àtẹ̀gùn apanirun,gẹ́gẹ́ bí àrọ̀ọ̀dá òjò àti òjò tí ómú ẹ̀kún omi wá,òun yóò fi tipátipá sọ ọ́ sílẹ̀.

3. Òdòdó-ẹ̀yẹ náà, tí í ṣe ìgbéraga àwọnọ̀mùtí Éfáímù,òun ni a ó tẹ̀ mọ́lẹ̀ lábẹ́ àtẹ́lẹṣẹ̀.

4. Òdòdó tí ó ń rọ náà tí í ṣe ẹwà ògo rẹ̀,tí ó tò sí orí àfonífojì ẹlẹ́tù lójú,yóò dàbí èso ọ̀pọ̀tọ́ tí ó pọ́n ṣáájú ìkóórèbí ẹnikẹ́ni bá ti rí i tí ó sì mú un ní ọwọ́ọ rẹ̀,òun a sì mì ín.

5. Ní ọjọ́ náà Olúwa àwọn ọmọ-ogunyóò jẹ́ adé tí ó lógo,Òdòdó tí ó lẹ́wàfún àwọn ènìyàn an rẹ̀ tí ó ṣẹ́kù.

6. Òun yóò sì jẹ́ ẹ̀mí ìdájọ́-òdodofún ẹni tí ó jókòó ní ìtẹ́-ìdájọ́àti oríṣun agbárafún àwọn ẹni tí ó ń dá ogun padàní ẹnubodè.

7. Àwọn wọ̀nyí pẹ̀lú ta gbọ̀n ọ́n gbọ̀n ọ́n fún ọtí wáìnìwọ́n pòòrì dànìn fún ọtí bíà,Àwọn àlùfáà àti wòlíì ta gbọ̀n ọ́n gbọ̀n ọ́n fún ọtí bíàwọ́n ta gíẹ́ gíẹ́ fún ọtí wáìnìwọ́n ń lọ́ bìrì bìrì fún ọtí bíà,wọ́n ta gbọ̀n-ọ́n gbọ̀n-ọ́n nígbà tí wọ́n ń ríran,wọ́n kọsẹ̀ nígbà tí wọ́n ń mú ìpinnu wá.

8. Gbogbo orí i tábìlì ni ó kún fún èébìkò sì sí ibìkan tí kò sí ẹ̀gbin.

Ka pipe ipin Àìsáyà 28