Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àìsáyà 26:13-21 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

13. Olúwa Ọlọ́run wa, àwọn olúwa mìírànlẹ́yìn rẹ ti jọba lé wa lórí,ṣùgbọ́n orúkọọ̀ rẹ nìkan ni àwa fi ọ̀wọ̀ fún.

14. Wọ́n ti kú báyìí, wọn ò sí láàyè mọ́;gbogbo ẹ̀mí tí ó ti kọjá lọ wọ̀nyí kò le dìde mọ́.Ìwọ jẹ́ wọ́n ní ìyà o sì sọ wọ́n di asán,Ìwọ pa gbogbo ìrántíi wọn rẹ́ pátapáta.

15. Ìwọ ti mú orílẹ̀ èdè gbòòrò, Olúwa;ìwọ ti mú orílẹ̀ èdè bí sí i.Ìwọ ti gba ògo fún araàrẹ;ìwọ ti sún gbogbo àwọn ààlà ilẹ̀ ṣẹ́yìn.

16. Olúwa, Wọ́n wá sọ́dọ̀ rẹ nínú ìpọ́njúu wọn;nígbà tí o jẹwọ́n ní ìyà,wọ́n tilẹ̀ fẹ́ ẹ̀ má le gbàdúrà kẹ́lẹ́ kẹ́lẹ́.

17. Gẹ́gẹ́ bí obìnrin tí ó lóyún tí ó sì fẹ́rẹ bímọtí í rúnra tí ó sì ń sunkún nínú ìrora rẹ̀,bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni àwa rí níwájúu rẹ Olúwa.

18. Àwa wà nínú oyún, a wà nínú ìroraṣùgbọ́n, afẹ́fẹ́ ni a bí lọ́mọ.Àwa kò mú ìgbàlà wá sí ilẹ̀ ayé;àwa kọ́ ni a bí àwọn ènìyàn tí ó wà láyé.

19. Ṣùgbọ́n àwọn òkúu yín yóò wà láàyèara wọn yóò dìde.Ìwọ tí o wà nínú erùpẹ̀,dìde nílẹ̀ kí o sì ké igbe ayọ̀.Ìrì rẹ dàbí ìrì òwúrọ̀,ayé yóò bí àwọn òkúu rẹ̀ lọ́mọ.

20. Ẹ lọ, ẹ̀yin ènìyàn mi, ẹ wọ ìyẹ̀wùu yín lọkí ẹ sì ti àwọn ìlẹ̀kùn lẹ́yìn in yín,ẹ fi ara yín pamọ́ fún ìgbà díẹ̀títí tí ìbínú un rẹ̀ yóò fi rékọjá.

21. Kíyèsíì, Olúwa ń jáde bọ̀ láti ibùgbé e rẹ̀láti jẹ àwọn ènìyàn ilẹ̀ ayé níìyà fún ẹ̀ṣẹ̀ẹ wọn.Ayé yóò sì sọ àwọn ẹ̀jẹ̀ tí a ta sí oríi rẹ̀,kì yóò sì fi àwọn tí a ti pa pamọ́ mọ́.

Ka pipe ipin Àìsáyà 26