Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àìsáyà 24:10-20 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

10. Ìlú tí a run ti dahoro,ẹnu ọ̀nà à bá wọlé kọ̀ọ̀kan ni a dí pa.

11. Ní òpópónà ni wọ́n ti ń kígbe fún wáìnìgbogbo ayọ̀ọ wọn ti di ìbànújẹ́,gbogbo àríyá ni a lé kúrò lórí ilẹ̀ ayé.

12. Ìlú ni a ti fi sílẹ̀ ní ahoro,ìlẹ̀kùn rẹ̀ ni a sì ti pa bámú bámú.

13. Bẹ́ẹ̀ ni yóò sì rí ní orí ilẹ̀ ayéàti láàrin àwọn orílẹ̀ èdè pẹ̀lú,gẹ́gẹ́ bí ìgbà tí a lu igi ólífì,tàbí gẹ́gẹ́ bí i pàǹtí tí ó ṣẹ́kù lẹ́yìntí a kórè èso tán.

14. Wọ́n gbé ohùn wọn ṣókè, wọ́n sì hó fún ayọ̀;láti ìwọ̀ oòrùn ni wọn yóò ti polongoọlá-ńlá Olúwa.

15. Nítorí náà ní ìlà oòrùn ẹ fi ògo fún Olúwa;gbé orúkọ Olúwa ga, àníỌlọ́run Ísírẹ́lì,ní àwọn erékùṣù ti inú òkun,

16. Láti òpin ayé wá ni a ti gbọ́ orin;“Ògo ni fún olódodo n nì.”Ṣùgbọ́n mo wí pé, “mo ṣègbé, mo ṣègbé!”“Ègbé ni fún mi!Alárékérekè dalẹ̀!Pẹ̀lú ìhàlẹ̀ ni àgàbàgebè fi dalẹ̀!”

17. Ìpáyà, isà-òkú, àti ìdẹkùn ń dúró dè ọ́,Ìwọ ènìyàn ilẹ̀ ayé.

18. Ẹnikẹ́ni tí ó bá sá nítorí ariwo ìpayàyóò ṣubú sínú ihò,ẹnikẹ́ni tí ó bá sì yọ́ jáde nínú ihòni ìdẹkùn yóò gbámú.Ibodè ọ̀run ti wà ní sísí sílẹ̀Ìpìlẹ̀ ayé mì tìtì.

19. Ilẹ̀ ayé ti fọ́ilẹ̀ ayé ti fọ́ dànù,a ti mi ilẹ̀ ayé rìrìrìrì.

20. Ilẹ̀ ayé yí gbiri bí ọ̀mùtí,ó bì síwá ṣẹ́yìn bí ahéré nínú afẹ́fẹ́;Ẹ̀bi ìṣọ̀tẹ̀ rẹ̀ ń pa á lẹ́rùtó bẹ́ẹ̀ tí ó fi ṣubú láìní lè dìde mọ́.

Ka pipe ipin Àìsáyà 24