Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àìsáyà 24:1-3 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Kíyèsí i, Olúwa yóò sọ ohungbogbo dòfo ní ilẹ̀ ayéyóò sì pa á runòun yóò pa ojúu rẹ̀ rẹ́yóò sì fọ́n àwọn olùgbé ibẹ̀ káàkiri—

2. bákan náà ni yóò sì rífún àlùfáà àti àwọn ènìyàn,fún ọ̀gá àti ọmọ ọ̀dọ̀,fún ìya-ilé àti ọmọbìnrin,fún olùtà àti olùrà,fún ayáni àti atọrọfún ayánilówó àti onígbésè.

3. Ilé ayé ni a ó sọ di ahoro pátapátaa ó sì jẹ gbogbo rẹ̀ run. Olúwa ni ó ti sọ ọ̀rọ̀ yìí.

Ka pipe ipin Àìsáyà 24