Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àìsáyà 23:1-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ọ̀rọ̀ ìmọ̀ tí ó kan Tírè:Pohùnréré, ìwọ ọkọ̀-ojú omi Táṣíṣì!Nítorí a ti pa Tírè runláìsí ilé tàbí èbúté.Láti ilẹ̀ Ṣáípúrọ́sì niọ̀rọ̀ ti wá sọ́dọ̀ wọn.

2. Dákẹ́ jẹ́ẹ́, ẹ̀yin ènìyàn erékùṣùàti ẹ̀yin oníṣòwò ti Sídónì,ẹ̀yin tí àwọn awẹ̀kun ti sọ dọlọ́rọ̀.

3. Láti orí àwọn omi ńláni irúgbìn oníhóró ti ilẹ̀ Ṣíhórì ti wáìkóórè ti Náì ni owóòná Tírè,òun sì ti di ibùjókòó ọjà fúnàwọn orílẹ̀ èdè.

4. Kí ojú kí ó tì ọ́, ìwọ Ṣídónì àti ìwọàní ìwọ ilé-ààbò ti òkun,nítorí òkun ti sọ̀rọ̀:“Èmi kò tí ì wà ní ipò ìrọbí tàbí ìbímọ ríÈmi kò tí ì wọ àwọn ọmọkùnrintàbí kí n tọ́ àwọn ọmọbìnrin dàgbà rí.”

5. Nígbà tí ọ̀rọ̀ bá dé Éjíbítì,wọn yóò wà ní ìpayínkeke nípaìròyìn láti Tírè.

6. Kọjá wá sí Táṣíṣì;pohùnréré, ẹ̀yin ènìyàn erékùṣù.

7. Ǹjẹ́ èyí náà ni ìlú àríyáa yín,ògbólógbòò ìlú náà,èyí tí ẹṣẹ̀ rẹ̀ ti sìn ín lọláti lọ tẹ̀dó sí ilẹ̀ tí ó jìnnà réré.

8. Ta ló gbérò èyí sí Tírè,ìlú aládé,àwọn oníṣòwò ẹni tí ó jẹ́ ọmọ aládétí àwọn oníṣòwò o wọ́n jẹ́ ìlúmọ̀míkání orílẹ̀ ayé?

9. Olúwa àwọn ọmọ-ogun ti ṣètò rẹ̀,láti tẹrí ìgbéraga àti ògo rẹ baàti láti rẹ gbogbo àwọn ọlọ́láilé ayé sílẹ̀.

10. Tu ilẹ̀ rẹ gẹ́gẹ́ bí i ti ipadò Náì,Ìwọ ọmọbìnrin Táṣíṣì,nítorí ìwọ kò ní èbúté mọ́.

11. Olúwa ti na ọwọ́ọ rẹ̀ jáde sí orí òkunó sì mú kí àwọn ilẹ̀ ọba wárìrì.Ó ti pa àṣẹ kan tí ó kan Fonísíàpé kí a pa ilé ààbò rẹ̀ run.

12. Ó wí pé, “Kò sí àríyá fún ọ mọ́”ìwọ wúndíá ti Ṣídónì, tí a ti tẹ̀rẹ́ báyìí!“Gbéra, rékọjá lọ sí Ṣáípúrọ́sì,níbẹ̀ pẹ̀lú o kì yóò ní ìsinmi.”

13. Bojú wo ilẹ̀ àwọn ará Bábílónì,àwọn ènìyàn tíkò jámọ́ nǹkankan bàyìíÀwọn Ásíríà ti sọ ọ́ diibùgbé àwọn ohun abẹ̀mí ihà;wọn ti gbé ilé ìṣọ́ ìtẹ̀gun wọn ṣókè,wọ́n ti tú odi rẹ̀ sí ìhòòhòwọ́n sì ti sọ ọ́ di ààtàn.

Ka pipe ipin Àìsáyà 23